Armed Robbery: Ọmọ Nàìjíríà mẹ́jọ gba ìdájọ́ ikú ní UAE

Awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, @TosinadedaMedia

Àkọlé àwòrán,

Awọn adigunjale

Ijọba orilẹede United Arab Emirate ti dajọ iku gbere fun ọmọ Naijiria mẹjọ lori ẹsun idigunjale.

Olugbani nimọran pataki fun aarẹ Naijiria lori ọrọ ilẹ okere atawọn ọmọ Naijiria to wa loke okun, Abike Dabiri-Erewa ti ṣapejuwe idajọ iku yii bi eyi to ṣe ni laanu jọjọ.

Ile ẹjọ to n gbẹjọ awọn ọdaran eyi to wa ni Sharjay ni UAE lo dajọ iku fawọn mọ Naijiria mẹjọ yii fun ẹsun ti wọn pe ni idigunlejale onipele pupọ (string of armed robbery).

Wọn ni wọn ji ọpọlọpọ nkan ni ajọ to n ri si pasiparọ owo ilẹ okere, wọn ji owo ni ẹrọ ATM atawọn ibomii ni orilẹede naa ni oṣu kejila ọdun 2016.

Àkọlé fídíò,

Abikẹ Dabiri: Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ Naptin àti àwọn aṣọ́bodè Nàìjíríà

Gẹgẹ bi ile iṣẹ iroyin kan ni UAE, Khaleel Times ṣe jabọ lọjọbọ ọṣẹ yii, ẹni to y ko ṣe ikẹsan wọn kan fi wọn oṣu mẹfa gbara ni tori owo ti wọn ji wa lọ́wọ́ rẹ.

Wọn yoo lee kuro pada wa si Naijiria to ba jiya ẹṣẹ rẹ tan lẹwọn.

Ninu ọrọ ti arabinrin Dabiri-Erewa sọ fun ile iṣẹ iroyin Naijiria kan, o ni "iṣẹlẹ to ṣe ni laanu ni, ṣugbọn kii ṣe iṣẹlẹ to juwe iru eniyan ti a jẹ".

Ile ẹjọ fi ẹsun idigunjale, fifi ipa da araalu laamu ati fifi ipa lọni lọwọ gba. Nigba ti awọn kan lara awọn ọdaran yii jẹwọ ẹṣẹ wọn, awọn kan ni awọn o jẹbi ẹsun naa.

Iwe iroyin English newspaper ni orilẹede UAE ni ọkan lara awọn ọdaran naa tilẹ ni oun ṣi le pe ẹjọ mii lori ẹjọ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti idajọ ti wọn fun oun yoo si dinku si ẹwọn gbere dipo idajọ iku.