Meghan and Harry: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ bí

Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, AFP

Lẹyin oṣu mọkanla ti wọn ṣe igbeyawo, Ọmọ ọba Sussex ati aya rẹ, Harry ati Meghan n reti ọmọ tuntun laipẹ.

Kinni a mọ nipa ọmọ ọba tuntun Ilẹ Gẹeṣi to n bọ yii?

Nigba wo ni wọn yoo bi ọmọ yii?

Meghan fun ra rẹ ti sọ tẹlẹ pe ipari oṣu kẹrin tabi ibẹrẹ oṣu karun un ọdun 2019 ni ọmọ tuntun yii yoo de.

Ohun to ku ni lati maa foju sọna si igba ti ọmọ naa yoo de.

Oríṣun àwòrán, Omo obabinrin Cambridge

Ṣe ọmọbinrin abi ọmọkunrin ni?

Ta lo mọ!

Ẹnikan ko tii mọ boya akọ tabi abo ni wọn yoo bi nitori wọn ko tii figba kan sọ iru ọmọ to wa ninu Meghan.

Meghan ti sọ fun awọn ololufẹ nigba to ṣabẹwo si agbegbe Merseyside pe awọn ko tii mọ boya akọ tabi abo lọmọ to wa ninu oun.

Nibo ni Meghan yoo bimọ si?

Ṣe ẹ ranti bi Ọmọ ọba William ati aya rẹ Catherine ṣe n jade lati ile iwosan St Mary's niluu London?

Oríṣun àwòrán, Samir Hussein

Awọn iwe iroyin kan sọ pe o ṣeeṣe ki Ọmọ ọba Harry ati aya rẹ maa bimọ sibẹ nitori ailefarapamọ nile iwosan ọhun.

Oríṣun àwòrán, Graham Prentice/Alamy

N jẹ ẹnikan mọ orukọ ọmọ yii?

Ibeere nla leyi, ko si ilana fun orukọ awọn ọmọ ọba Ilẹ Gẹẹsi.

Oríṣun àwòrán, Martin Keene/PA

Orukọ baba rẹ n kọ?

Ọmọ yii le maa nilo orukọ baba rẹ nitori ọmọba tabi ọmọbabinrin ni yoo maa jẹ nigba ti wọn ba bii.

N jẹ ọmọ yii le di ọba ile Gẹẹsi lọjọ iwaju?

Oríṣun àwòrán, Tim Graham

Bẹẹ ni ṣugbọn awọn ọmọ ọba mẹfa lo wa nilẹ siwaju rẹ ti awọn naa le jọba.

Njẹ ọmọ yii le jẹ ọmọbibi ilẹ Amẹrika?

Oríṣun àwòrán, James D. Morgan

Bẹẹ ni, nitori ọmọ ilẹ Amẹrika ṣi ni mama rẹ Meghan, fun idi eyi, ọmọ naa laṣẹ lati jẹ ọmọbibi orilẹede Amẹrika.

Bakan naa, ọmọ yii yoo laṣẹ lati jẹ ọmọ orilẹede meji nitori baba rẹ Harry jẹ ọmọ ilẹ Gẹẹsi.