Nigeria Election Update: 'Ilé iṣẹ́ DSS kò mú òṣìṣẹ́ INEC kankan lórí ẹ̀sùn Atiku'

Atiku Abubakar

Irọ ni wọn n gbe kiri! Ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS ti sọ pe iroyin ofege lawọn kan n gbe kaakiri pe ajọ naa ti mu awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC kan.

Iroyin to lu oju ayelujara pa ni pe awọn oṣiṣe INEC fun oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar lanfani lati ri awọn ohun elo idibo aarẹ lori ẹrọ kọmputa INEC.

Ninu atẹjade ti ile iṣẹ DSS fi sita, eyi to si loju opo Twitter ajọ INEC, DSS ni ko si otitọ kan ninu iroyin miran to tun sọ pe ajọ na mu oṣiṣẹ INEC meja, wọn si fiya jẹ wọn fun ọjọ mẹta ki wọn le jẹwọ bi ọrọ naa ṣe jẹ gan an.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Àkọlé fídíò,

Hakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

Atiku ti sọ tẹlẹ pe oun ṣetan lati kọwọ rin pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ onimọ ẹrọ Kọmputa lọ sibi igbẹjọ lori idibo aarẹ to kọja lọ ti o pe.

Bẹẹ lo sọ pe awọn eeyan ni wọn yoo fidi nọmba ẹrọ kọmputa to sọ pe ajọ INEC fihan oun nibi to ni oun ti rii pe PDP lo jawe olubori ninu ibo aarẹ to lọ.

Ọgbẹni Peter Afunanya to buwọ lu atẹjade DSS ti INEC fi sita sọ pe awọn ti wọn fẹ da rogbodiyan silẹ ni wọn n gbe iru iroyin ofege yii kaakiri.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati kọ eti ikun si iroyin naa.