Kelechi AFC: Ojúlówó alátìlẹyìn Arsenal n kí ìran Yorùbá fún ọdún Ajinde

Kelechi AFC: Ojúlówó alátìlẹyìn Arsenal n kí ìran Yorùbá fún ọdún Ajinde

Loni tii ṣe ọdun Ajinde, a mu ikini pataki wa lati ọdọ ilumọka ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal,Dokita Kelechi Anyikude wa fun yin.

Ti ẹ ba j ẹni to n fi ọkan tele ere bọọlu paapa julọ ni English Premiership, ẹ o ti ri Dokita Kelelchi pẹlu irukẹrẹ lọwọ nibi ti o ti n fi ifẹ han si ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal

Ilu London ni Dokita Kelechi fi ṣe ibujukọ o si jẹ ọmọ iran Igbo.

Ẹ ma ṣe jẹ ki o ya yin lẹnu pe o bọwọ pupọ fun orileede Naijiria ti kii si j'afara lati gbe ogo ilu rẹ ga nibi kibi to ba wa.

Yoruba rẹ ko fi taratata dan daada ṣugbọn ni ibamu pẹlu ifẹ ati ibaṣepọ ti ọdun yi kọwa, o da wa loju wi pe ẹ o nifẹ́ si ikini rẹ yi.