Marina-Eko Bridge: Ìjọba gbóṣùbà fún àtìlẹyìn aráàlú lásìkò tí wọn ti afárá méjèèjì pa

Bridge

Oríṣun àwòrán, Federal government

Ijọba apapọ Naijiria ti kede pe afara Marina ati Eko yoo di sisi pada lati ọjọ Aje ọla.Atẹjade kan ti wọn fisita nilu Abuja lo sísọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe, iṣẹ atunse afara mejeeji naa ti buse.Atẹjade ọhun tun salaye pe iṣẹ atunse yoo bẹrẹ lọgan loju ọna Alaka, tijọba si tun gboriyin fáwọn araalu fun atilẹyin ati suuru wọn lasiko ti isẹ atunse naa n lọ lọwọ.

Bẹẹ ba gbagbe, lati oṣù kẹta ọdun 2020 nijọba apapọ ti ti afara Eko pa lati ṣe atunse rẹ ko to dẹnu kọlẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àwọn àrá ìlú fi èrò wọn hàn lórí afárá 3rd Mainland tí ìjọba tì

Awọn awakọ ati awọn arinrinajo ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori ẹrọ ayelujara nitori inira ti wọn la kọja lori afara Third mainland ti ijọba ti.

Alẹ Ọjọ Ẹti ni ijọba ti afara naa ni ọna mẹjeeji amọ ti wọn si fi alakalẹ lede lori igba ati akoko ti awọn eniyan yoo fi le ma a raaye kọja nibẹ ni ojoojumọ.

Ọpọlọpọ awọn to faraya ninu awọn eniyan naa sọ wi pe owo ọkọ wọn, ati wi pe awọn ibi ti wọn n gbe ni igba Naira tẹlẹ, awọn awakọ ti sọ di ẹgbẹrun Naira kan.

Bakan naa ni awọn eniyan ke irọra pẹlu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti awọn ọlọkọ ajagbe da silẹ ni ọpọpọna afara Eko Bridge ni ibi to tun yẹ ki awọn eniyan ma a gba kọja.

Ninu ọrọ tirẹ, Ogbeni Dami ni awọn ole ti bẹrẹ si ni ṣọṣẹ lori afara third mainland naa ati awọn ọna miran ti ijọba lakalẹ fun awọn eniyan lati ma a gba.

Nitori naa ni wọn ṣe ke gbajare si ijọba ipinlẹ Eko lati ri pe eto aabo gbokun si lasiko yii nitori awọn janduku yoo mu aye le fun awọn eniyan lasiko ti wọn ba n wa ọna ati jẹ ati mu lọ.

Awọn miran ti lẹ fi awọran bi awọn eniyan ṣe pejọ si papakọ BRT ti awọn eniyan ti fẹ wọ ọkọ ni agbegbe Ikorodu, ti wọn si tun fihan pe ko si yiyago fun ara ẹni laaarin awọn eniyan to n tiraka lati wọ ọkọ.

Amọ, a ri awọn miran to sọ wi pe inu wọn dun si afara thrid mainland ti ijọba ti naa nitori ọpọlọpọ ileeṣẹ lo ti wa paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ wọn lati ṣiṣẹ lati ile, eleyii to mu irọrun ba awọn eniyan.

Ijọba apapọ ni idi fi awọn fi ti afara third mainland naa ni lati ṣe atunṣe oni igba de igba ti wọn ma n sẹ ki afara naa ma ba a da ijamba silẹ fun awọn eniyan to n gba ibẹ .

Afara Third manland bridge naa ni afara keji to gun julọ ni ilẹ Afrika, o si di Osu Kini, ọdun 2021 ki wọn to ṣi i pada.

Wo ohun tí aráàlú ń kojú lọ́jọ́ Aje àkọ́kọ́ tí wọn ti 3rd Mainland

Ni idaji kutukutu ọjọ Aje ni ikọ iroyin BBC Yoruba ti jade lati mọ bi eto irinna yoo ti rọrun tabi nira si fun awọn awakọ nilu Eko.

Àkọlé àwòrán,

Sunkẹrẹ fakẹrẹ

Idi ni pe oni ni ọjọ Aje akọkọ, tii tun se ọjọ kẹta tijọba apapọ bẹrẹ isẹ atunse lori abala kan lori afara Third Mainland, eyi ti wọn ti pa.

Osu mẹfa gbako si ni atunse abala mejeeji afara naa yoo fi waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko abẹwo BBC Yoruba si awọn adugbo bii Stadium, Ipọnrin, Shitta, titi wa si adugbo Oworonsoki, a sakiyesi pe lati aago mẹrin owurọ ni awọn ọkọ ti gbemu-lemu.

Àkọlé fídíò,

Africa Eye: Coronavirus di adákẹ́jà ní Somalia, ikú ọ̀wọ́ọ̀wọ́ ń peléke si

Ọpọ awakọ to si fẹ gba ori afara naa kọja lo tete bẹ sita lai naani pe ilẹ si dudu, koda, oju ọna to lọ si Ikoyi gan ti kun fun ọpọ ọkọ lati aago mẹrin abọ owurọ.

Akọroyin BBC to kọja lori afara naa ni opin ọsẹ ni nnkan ti yatọ si ti tẹlẹ gẹgẹ bi òun ti oju.

Oju ọna to wa lati Iyana Oworo nikan lo wa ni ṣíṣí titi de Adeniyi-Adele, awọn ọkọ to ba n bọ lati ọna Iyana Oworo nìkan lo ni anfaani lati gba ori afara naa laarin aago mejila oru si aago kan ọsan.

Eyi tumọ si pe, awọn ọna miran ni awọn to n bọ lati Lagos Island lọ si ọna Iyana Oworo, yoo gba laarin asiko yii.

Sugbọn to ba ti di aago kan ọsan si mejila oru, awọn to n bọ lati Lagos Island nìkan ni yoo le lo ori afara, ti iyatọ diẹ si wa nibẹ.

Ni kete ti wọn ba de Adeniyi Adele, ni wọn yoo fi oju ọna ti wọn silẹ, lati ya si oju ọna to wa lati Iyana Oworo. Àwọn oṣiṣẹ to n sisẹ lori afara naa ti la ọna kan nibẹ fun eyi.

Oríṣun àwòrán, LASG

Àkọlé àwòrán,

Gov Sanwo-Olu fi kun pé àwọn ọkọ èrò ńlanla ẹgbẹ̀ta yóò wo ìlú Eko ni inú oṣù kẹjọ

Ojú ọna naa ni wọn o tọ titi de Iyana Adekunle, nibi ti awọn to n bọ lati ọna Ebute Mẹta n gba jade, ki wọn o tun to ya nibi ti wọn ti la silẹ laarin meji afara, pada si ọna Iyana Oworo.

Lasiko yii, ko si ọna fun awọn to n bọ lati Mainland lati gba ori afara.

Nkan ti a ṣe akiyesi ni pe, yíyà lati ibi kan si ekeji n fa sunkẹrẹ, fakẹrẹ ọkọ.

Sugbọn, àwọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA, ati FRSC wa nibẹ lati ma a dari.

Àmọ́, ó ṣeé ṣe ki sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ko lagbara laarin ọsẹ ju opin ọsẹ ti a sọ yii, nitori pe ọkọ má n pọ ni oju ọna.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Govt of Nigeria

Nkan miran tun ni pe ẹsẹ ni awọn eeyan kan fi n rin lati Iyana Oworo ni irọlẹ ti akọroyin BBC kọja.

O ṣeé ṣe ko ko jẹ nitori aisi ọkọ to n bọ lati ibẹ, tabi nitori pe wọn o fẹ ẹ lọ gba ọna to jin de Lagos Island ni wọn ṣe ko ẹsẹ si.

Ju gbogbo ẹ lọ, ẹ fi si ọkàn, yala gẹgẹ bi awakọ tabi eero ọkọ, pe o ṣe e ṣe ki ẹ há sinu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lasiko ti atunse afara Third Mainland Bridge.

Wo ọna abayọ lọwọ sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ bi ijọba se ti afara Third mainland:

Oríṣun àwòrán, LASG

Ọjọ́ Ajé ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ọṣù keje, ọdún 2020 ti àwọn olúgbé ìpińlẹ̀ Eko yóò mọ ìpa ti àpá kan afára 3rd mainland tí ìjọba ti pa yóò ṣe ko ìnira ba àwọn arfá ìlú tó.

Tí ẹ o bá gbàgbé , oṣù mẹ́fà ni àfárá náà yóò fi wà bẹ́ẹ̀.

Gómìnà ìpińlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ti wá kédé pé láìpẹ́ yìí ni ìjọbna yóò ṣe àfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ojú omí mẹ́fà míràn láti fún àwọn ará Eko ni ìwúrí láti ma wọ ọkọ̀ ojú omi fún oṣù mẹ́ta tó n bọ̀ yìí.

Èyí wáyé lẹ́yìn ti ìjọba àpapọ̀ kò yí ẹnu pada lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ti 3rd Mainland fún oṣù mẹ́fa lati ṣe àwọn àtúnṣe yẹ ti yóò sì bẹ̀rẹ̀ lónìí ọjọ́ kẹrìndinlọ́gbọ̀n ọṣù kèje, ọdún 2020.

Oríṣun àwòrán, LASG

Bí o lé rìn láàrin Eko pẹ̀lú Ferry

Ní oṣù keji ọdún ni ìjọba Ipinle Eko kede aapu ti won n lo fun awon to n wo ferry lái le jẹ́ ki àwọn ènìyàn máá ṣàmúlò ìrìn ojúomi ní ìlú Eko. Bótilẹ̀ jẹ́ pé kò ti si àridáju ààpu òun lórí Aplle Appstore tabi lori Goggle Playstore.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ọ̀ná bi ọgbọ̀n ló wà lójú omi ti ènìyàn le gbà:

 • Ajah - Five Cowries - Marina/C.M.S
 • Badore - Five Cowries
 • Badore - Ijede
 • Baiyeku - Ajah
 • Baiyeku - Victoria Island
 • Ebute Ero - Ikorodu
 • Ebute Ojo - Ijegun Egba - Marina C.M.S
 • Ijede - Marina C.M.S
 • Ikorodu - Addax/Falomo
 • Liverpool - Igbo Elejo
 • Liverpool - Olodi Apapa
 • Marina/C.M.S - Ikorodu
 • Baiyeku - Langbasa
 • Ebute Ojo - Ibasa
 • Ebute Ojo - Ijegun Egba
 • Ebute Ojo - Irewe
 • Ijegun Egba - Ibasa
 • Liverpool - Five Cowries
 • Marina/C.M.S - Liverpool
 • Agboyi Ketu - Five Cowries
 • Agboyi Ketu - Marina/C.M.S
 • Agboyi Ketu - Mile 12
 • Ajah - Oworonshoki
 • Ijora - Ebute Ero
 • Ikorodu - Oworonshoki
 • Marina/C.M.S - Oworonshoki
 • Mile 2 - Addax/Falomo
 • Mile 2 - Marina/C.M.S
 • Oworonshoki - Ebute Ero
 • Oworonsoki - Five Cowries

Owó ọkọ̀ ojú omí kò ju ẹ̀dẹ́gbẹ́ta naira sí ẹgbẹ̀run kan naira ló, sùgbọ́n fún ẹ̀kúnrẹrẹ àláyé lórí bi owó náà ṣe jẹ́ wan ojú òpó twitter ìjóba ìpínlẹ̀ Eko yìí:

Àkọlé àwòrán,

Third mainland bridge mo foo

Àwọn ibi ti ọkọ̀ ojú omi máa n ná

Ọ̀pọ̀ ni ìbẹ̀ru ti mú pe'súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ lọ́la ọjọ́ ajé yóò lóyun sinu, yóò pọmọ kódà yóò tún fa báàgì.

Ó lè jẹ́ ìdí nìyí ti gómìnà fi rs àwọn ará ìlú láti maa sàmúlò ojú omi, nínú àtẹjáde kan ti àgbẹnusọ rẹ̀ Gboyega Akosile buwọlù lánà òdé yìí.

Wọ́n ti ti apá kan afara náà láti owúrọ̀ ọjọ́ sátide, kò si si àniàni súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ yóò pọ̀, nítori naa o lé jẹ́ ojú omi ni ọ̀na àbáyọ láti sá fun wàh'\alà ojú pópó tó n bọ̀ yìí.

Third Mainland Closure: Wo ǹkan ti ojú àwọn ènìyàn ń rí lórí àfára 3rd Mainland

Àkọlé àwòrán,

Sunkẹrẹ fakẹrẹ

Lorumọju oni ọjọ Abamẹta ni ijọba apapọ ti ori afara Third Mainland gẹgẹ bi wọn ṣe kede ṣaaju.

Oṣu mẹfa gbako si ni wọn kede pe wọn a fi ṣiṣẹ lori afara naa.

Wọn yoo ti apa kan fun oṣu mẹta akọkọ ati apa keji fun oṣu mẹta miran.

Ọpọ awakọ lo ti tete rinrinajo kuro ni erekuṣu to jẹ Island lọ si Mainland ki aago mejila ti ijọba kede to lu lalẹ ọjọ Eti nigba ti awọn to ni nkan ṣe lopin ọsẹ yii naa ti de lati Mainland nitori ibẹru sunkéré-fakẹrẹ ọkọ.

Owo gọbọi ni awọn agbero ati ọlọkọ gbe awọn ero ni alẹ ana ọjọ Ẹti nitori ọpọ ero to wa ni titi ti wọn ko fẹ ki awọn ṣe kongẹ idamu ọrọ afara titunṣe naa.

Sanwo Olu to n tukọ ipinlẹ Eko ti fi da awọn eeyan loju pe inira naa ko ni pọ ju nitori pe ijọb eti ṣeto silẹ ko ma ga ju ara lọ.

O ni yatọ si pe awọn ọn abuja miran ti wa lati gba lasiko iṣẹ atunṣe yii.

Ijọba ti tun awọn ọna gbegbe kọọkan ṣe ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ le dinku ni awọn ẹkun naa.

O tun kede pe awọn oṣiṣẹ oju popo LASTMA aadọta ati ọgọrun un mẹfa ni yoo wa nibẹ lati maa ri si lilọ bibọ ọkọ.

Koda, oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo aadọta ati igba FRSC ni yoo ṣiṣẹ ko ma baa si sunkẹrẹ-fakẹre ọkọ lasiko naa.

Pataki Afara 'Third Mainland Bridge' ati itan rẹ:

Afara yii jẹ eyi ti wọn tun n pe ni Ibrahim Babangida Boulevard, ọjọ ibi Babangida lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ lọdun 1990 ni wọn ṣii.

Ohun ni afara to gun julọ nipinlẹ Eko to jẹ olu ilu Naijiria tẹlẹ ki wọn to koo lọ si Abuja.

Afara yii gun fun iwon kilomita 11 ati mẹjọ. (11.8 km).

Àkọlé fídíò,

Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Afara 'Third Mainland' to jẹ ikẹta yii jẹ eyi to gun ju ninu awọn afara to so Mainland Eko pẹlu Erekusu Island Eko papọ, iyẹn afara Carter ati afara Eko.

Eyi to tumọ si pe ohun lo so agbegbe ọrọ aje ilu Eko mọ ti Mainland.

Eko ni o kun fun ero julọ nilẹ Adulawọ.

Laye iṣejọba Ogagun Ibrahim Babangida ati Ọgagun Raji - Rasaki to n tukọ ipinlẹ Eko nigba naa ni wọn kọọ laarin ọdun 1976 si ọdun 1980 ni apa akọkọ ti apa keji si jẹ 1988 si 1990.

Afara yii lo gun ju nilẹ Adulawọ lasiko ti wọn ṣii, o bẹrẹ lati Oworonṣoki to ja si opopona Apapa-Oshodi ati opopona Eko si Ibadan pọ.

Afara yii gba ọkọ mẹjọ papọ lẹgbẹkẹgbẹ, o si ṣafihan ilu eko lati or omi to fi kan Fasiti Eko ati Makoko lori omi.

Ijọba Babangida ko na Biliọnu kan naira tan to fi pari rẹ lẹyin ti awọn kan yọwọ ninu rẹ.

Lọdun 2013, o le ni biliọnu kan naira ti wọn fi tun apa kan

Wo àwọn ọ̀nà míràn tí o leè gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti afára Third Mainland

Alakoso ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri ọrọ iṣẹ agbegbe, Olukayode Popoola ti sọ pe ijọba ko ni boju wẹyin tabi sun ọjọ siwaju lori atunṣe afara Third Mainland to wa ni ilu Eko.

Atunṣẹ afara naa yoo bẹrẹ ni oru ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje ọdun 2020, ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti n bere pe, ṣe awọn olugbe Eko ti ṣetan fun idojukọ ti yoo waye nitori atunṣẹ naa.

Popoola sọ pe ijọba ti ṣe atunṣe awọn ọna miran ti awọn eeyan le maa gba lasiko ti iṣẹ ba n lọ lọwọ lori afara Third Mainland.

Òru òní ní ìjọba á ti afárá 'Third Mainland' ní Eko; Wo àwọn ọ̀nà míràn tí o leè gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá tìí

Wo àwọn ọ̀nà míràn tí o leè gbà lẹ́yìn òru òní tí àtúnṣe afára Third Mainland á bẹ̀rẹ̀

Ọpọ eeyan lo n kọminu boya ijọba Naijiria ati ti ipinlẹ eko le kaju iṣoro to le tẹlẹ titi afara nla yii pa lasiko yii.

Ṣugbọn, ọga agba to n mojuto iṣẹ akanṣe naa, Ogbeni Popoọla ṣalaye pe didun lọsan atunṣe naa yoo so fawọn olugbe ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò,

Peters Ijagbemi dá àrá lórí ètò 'Ṣé o láyà' ti BBC Yorùbá lọ̀sẹ̀ yìí

Wo awọn ọna abuja miran ti o le gba lai gba afara Third Mainland

Ijọba ti ṣeto awọn ọna miran ti awakọ le gab lasiko ti iṣẹ atunṣe ṣi n lọ lọwọ lori afara yii

Oríṣun àwòrán, LASG

Fun apẹẹrẹ, o ni opopona Addo/Oyingbo/Adekunle/Ebutte Metta ti wa ni sẹpẹ ti awọn eeyan le maa gba.

Bẹẹ lo tun sọ pe ọna Ikorodu si Maryland naa ti di lilo lẹyin ti ijọba ṣe atunṣẹ rẹ.

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ n lọ lọwọ ni opopona Maryland

Ijọba ipinlẹ Eko ti rọ awọn to n gba ori afara naa lati ma foya, nitori abala kan yoo wa fun lilo lori afara ọhun.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ agbegbe ni ipinle Eko ni opopona to lọ si Oworonsoki ni yoo kọkọ di titi pa fun oṣu mẹta, lẹyin ti iṣẹ abala naa ba pari ni wọn yoo sun si iha Island.

Abẹwo ileeṣẹ iroyin BBC kaakiri ilu Eko fi han pe lootọ ni ijọba Eko ti n ṣatunṣẹ ọna Maryland atawọn opopona miran to sọ.

Àkọlé fídíò,

Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Wo iye tí ọkọ̀ òfurufú náà yóò máa gbé èrò láti MM1 sí Island

Oríṣun àwòrán, others

Làìpẹ́ yìí ni ìjọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Eko ti kede pé àwọn yóò gbé afára 3rd Mailand tì pa fun oṣù mẹ́fà lójúnà àti ṣe àtúnṣe sí àwọn ibi tó mẹ́hẹ nibẹ fún ìgbáyégbádùn àwọn ará ìlú.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ti wá ọna abayọ si sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lasiko ti iṣẹ ba n lọ lori afara Third Mainland ti wọn fẹ tunṣe ni ilu Eko.

Àwọn ilé iṣẹ́ kan ti kéde pẹ̀lú pé àwọn ni ọ̀nà àbáyọ míràn, wọ́n ni àwọn ti ṣe ètò láti máa fí ọkọ̀ òfurufu.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ ọkan lára àwọn tó ń bá alábàráà sọ̀rọ̀ fún ilé iṣẹ́ náà Nonye sàlàyé pé ọkọ̀ òfurufú (Helicopter) náà yóò má gbé ènìyàn mẹ́jọ ni ìrìn ẹ̀ẹ̀kan.

Bákan náà ló sàlàyé pé owó èrò kọ̀ọ̀kan yóò máa jẹ́ ẹ̀ẹ́gbẹ́tà dọ́là (#200, 000), ìyẹn ẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ìgbá Naira.

Ó ní ọkọ̀ náà yóò máa gbéra láti pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed Way sí Ozumba Mbadiwe láti ààgo méje owúrọ tit di ààgo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́

Sùgbọ́n ìbéèrè ni pé, ènìyàn mélòó ni ètò yìí le ṣe ìrànwọ́ fún láàrin oṣù mẹ́fà ti ìjọba yóò fi ti pápákọ̀ òfurufu.

Ènìyàn

Third Mainland Bridge: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde bí àtúnṣe afárá Third Mainland yóò ṣe wáyé

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Ọdun 2018 ni wọn ti afara ọhun kẹyin fun ọjọ mẹta lọna ati ṣe iwadii awọn iha to ti n dẹnukọlẹ lori rẹ

Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Eko ti kede ọna abayọ si sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lasiko ti iṣẹ ba n lọ lori afara Third Mainland ti wọn fẹ tunṣe ni ilu Eko.

Nigba ti wọn n sọrọ nibi ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni ipinlẹ naa, wọn ni awọn ti ṣeto biara ilu ṣe le maa gba ori afara naa lasiko atunṣe ọhun.

Lara awọn to wa nibi apero naa ni adari ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ agbegbe ipinlẹ Eko, Olukayode Popoola; kọmiṣọnna eto irinna, Frederic Oladeinde ati olubadamọran pataki fun Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ iṣẹ, Aramide Adeyoye.

Wọn ni abala akọkọ atunsẹ afara ọhun yoo waye fun oṣu mẹta, nigba ti abala atunṣẹ keji yoo waye fun oṣu mẹta miran.

Bayii ni wọn ṣe ṣeto bi awọn eeyan yoo ṣe maa gba ori afara naa nigba ti atunṣe ba n lọ lọwọ:

Oṣu mẹta akọkọ yoo wa fun atunṣẹ ọna to lọ si Oworonsoki lati lori afara Third Mainland.

Lasiko yii, awọn awakọ yoo maa gba ọna kan naa lati aago mejila oru si aago kan ọsan.

Nigba ti awọn awakọ yoo maa gba ọna to wa lati Lagos Island si Oworonsoki ni abala to lọ si Lagos Island lati aago kan ọsan si mejila oru.

Oríṣun àwòrán, @ericotrips

Oṣu mẹta to tẹle eyi yoo wa fun atunṣe ọna to lọ si Lagos Island lori afara naa.

Lasiko yii ni awọn awakọ yoo si maa gba abala ọna ori afara ọhun to wa lati Oworonsoki si Lagos Island, ni abala ọna naa to lọ si Lagos Island, lati aago mejila oru si aago kan ọsan.

Nigba ti awọn awakọ yoo si maa gba abala to wa lati Lagos Island si Oworonsoki ni ọna to kọju si Oworonsoki, lati aago kan ọsan si mejila oru.

Kọmiṣọnna eto irinna, Frederic Oladeinde sọ pe ijọba yoo fun awọn to n bọ lati Mainland si Island laaye ati gba ori afara ọhun ni aarọ ati ọsan nigba ti awọn ọkọ to n bọ niwaju yoo ni lati lọ gba ọna miran.

Bakan naa lo gba imọran pe ki awọn eeyan maa lo ọkọ oju omi bii lati Ikorodu si Mile 2 ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò,

Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran

Oladeinde fi kun un pe ijọba yoo pese awọn ọkọ akero lọpọ yanturu ki awọn eeyan le fi ọkọ wọn silẹ nile lọna ati ṣadinku ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ loju popo.

Kọmiṣọnna naa pari ọrọ rẹ pe ki awọn eeyan joko sile to ba ṣeeṣe ki ọkọ le dinku loju popo lasiko atunṣe afara naa.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Ọdun 2018 ni wọn ti afara ọhun kẹyin fun ọjọ mẹta lọna ati ṣe iwadii awọn iha to ti n dẹnukọlẹ lori rẹ

July 24 ní ìjọba àpapọ̀ yóò ti afárá Third Mainland fún àtúnṣe

Ijọba apapọ Naijiria ti n gbaradi lati ti afara Third Mainland to wa ni ipinlẹ Eko fun oṣu mẹfa lọna ati bẹrẹ iṣẹ atunṣe lori rẹ.

Adari ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ agbegbe, Olukayode Popoola lo fi ọrọ naa lede lọjọ Aje.

Popoola sọ pe "A fẹ bẹrẹ atunse afara Third Mainland laipẹ, o si ṣeeṣe ki a ti afara ọhun lati ọjọ kẹrinlelogun oṣu keje ọdun yii."

O ni gbogbo irinṣẹ ti wọn nilo lati tun afara naa ṣe lo ti wọle si orilẹ-ede Najiria, nitori naa ijọba yoo bẹrẹ iṣẹ ọhun ni kankan.

Popoola sọ pe eto ti n lọ lọwọ lati wa ojutu si sunkẹrẹ-fakẹrẹ ti yoo waye lẹyin ti iṣẹ naa ba bẹrẹ.

O ni lẹyin ti eto ọhun ba ti to tan ni awọn oṣiṣẹ yoo lọ bẹrẹ iṣẹ lori afara naa.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin NAN ṣe sọ, ọdun 2018 ni wọn ti afara ọhun kẹyin fun ọjọ mẹta lọna ati ṣe iwadii awọn iha to ti n dẹnukọlẹ lori rẹ.

Ṣugbọn diẹ lara awọn ohun elo ti wọn yoo fi ṣatunsẹ afara ọhun ko si lorilẹ-ede Naijria ni ijọba ṣe pinnu lati ko wọle lati oke okun.

Afara naa ti wọn ṣi lọdun 1996 lo nasẹ ju ninu awọn afara mẹta to so agbegbe Lagos Island ati mainland pọ ni ipinlẹ Eko.

Ìjọba fọkàn àwọn olùgbé ìlú Eko balẹ̀ lórí afárá

Ẹka ijọba to n ri si ọrọ ina mọnamọna, iṣẹ ṣiṣe ati ile gbigbe ti kede wi pe ko sewu pẹlu afara Third Mainland niluu Eko.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Hakeem Bello to jẹ oludamọran pataki si Minista ẹka naa, Babatunde Faṣọla fi sita lọjọ Aiku lo ti sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò,

'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

O ni ile iṣẹ ijọba naa ni kawọn olugbe ilu Eko maa bẹru lori iroyin kan to gba oju Facebook pe afara naa ti ni iyọnu lawọn ibi kan.

Ilẹ iṣẹ ijọba ṣalaye ninu atẹjade naa pe atunṣẹ yoo waye lori awọn ibi ti wọn ti so afara naa pọ ti wọn mẹnu ba ninu fidio ti awọn kan fihan loju opo Facebook.

Wọn ṣalaye ninu atẹjade naa pe awọn onimọ ẹrọ nipa ọna ṣiṣe ni awọn bi ti wọn ti so afara naa pọ yii to nilo atunṣe ko le ṣakoba fun afara ọhun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Govt of Nigeria

Ti ẹ ko ba gbage, ninu oṣu kẹjọ ọdun 2018 ni ijọba apapọ ti afara Third Mainland fun ọjọ mẹta fun ayẹwo.

Ko da ayẹwo lati inu omi tun waye lori afara naa ninu oṣu kẹta ọdun lati ni idaniloju awọn ibi to nilo atunṣe lori afara naa.

Afara Third Mainland lo gun ju lọ ninu awọn afara mẹta to lọ si erkusu ilu Eko, awọn meji to ku ni Eko Bridge ati Carter Bridge.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ