Sri Lanka attack: Orílẹ̀èdè mẹjọ, yàtọ̀ sí Sri lanka ló pàdánù èèyàn wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Obinrin kan bú sẹkun nitori ẹbi rẹ kan ku ninu iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ile ijọsin mẹta ni wọn ṣe ikọlu si ni ọjọ Ajinde

Àwọn to gbẹmii mi ninu ikọlu ado oloro to ṣẹlẹ ni awọn ile ijọsin mẹta ati awọn ile igbafẹ kan ni Sri Lanka ni ọjọ Ajinde, ti di ọọdunrun o din mẹwaa bayii. Ọpọlọpọọ wọn si lo jẹ ọmọ orilẹede Sri Lanka.

Ileesẹ ọlọpaa orilẹede naa ni awọn mẹrinlelogun ni ọwọ ti ba bayii lori ikọlu naa, ṣugbọn ko tii ye awọn alaṣẹ nipa awọn eeyan to ṣe agbatẹru ikọlu naa.

Eniyan bii ẹẹdẹgbẹta lo fara pa, ti awọn ajoji to wa lara awọn to ku si to marundinlogoji.

Àwọn ìròyìn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Orilẹede awọn ajoji to ku ti wọn ti ri rèé:

  • Ilẹ Gẹẹsi - 5
  • Denmark - 3
  • Portugal - 1
  • India - 6
  • Turkey - 2
  • China - 2
  • Netherlands - 1
  • Japan - 1

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Àwọn alufaa ni ile ijọsin St Anthony to wa ni Kochchikade

Ọpọlọpọ oku awọn ajoji to fara kaaṣa iṣẹlẹ naa ni wọn ko ti i ri.

Ikọlu ọjọ Ajinde naa wa lara eyi to buru ju to ṣẹlẹ ni Sri Lanka ri lati igba ti ogun abẹle orilẹede naa ti pari ni 2009.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn ẹlẹsin Kristiani ko pọ ni Sri Lanka

Lẹyin ikọlu naa ni ọjọ Aiku, olori orilẹede naa, Ranil Wickremesinghe ni awọn agbofinro mọ wipe ikọlu le waye, ṣugbọn wọn ko gbe igbesẹ kankan lori ọrọ naa ki o to ṣẹlẹ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Iroyin to kọkọ wọle fi han wipe, ado oloro kan bu ni bii aago mẹsan ku iṣeju marundinlogun ti awọn mẹfa miiran si tẹle.

Ile ijọsin mẹta ni Negombo, Batticaloa ati agbegbe Kochchikade ni awọn ikọlu naa ti waye nigba ti isin Ajinde n lọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ile ijọsin St Sebastian's to wa ni Negombo ba jẹ tori ado oloro naa

Awọn ile igbafẹ ti wọn tun sọ ado oloro si ni Shangri-La, Kingsbury and Cinnamon to wa ni olu ilu orilẹee naa.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ado oloro ba ile igbafẹ Shangri-La jẹ ni Colombo

Ado oloro kẹjọ ti o bu ni agbegbe Dematagoda nigba ti ọlọpaa lọ mu awọn kan pa ọlọpaa mẹta.