Faye Mooney: Ìlú Eko ló ti lọ sóde àríyá ní Kaduna ni wọ́n yìnbọn fun

Awọn gende agbebọn meji

Oríṣun àwòrán, @thenewsnigeria

Ọlọrun ma jẹ ka rin ni ọjọ ti ebi yoo pa ọna tabi ti a se agbako iku ojiji.

Obinrin ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, Faye Mooney lo ti se alabapade iku ojiji rẹ ni ilu Kaduna lasiko to lọ se ariya lati ilu Eko.

Ibudo igbafẹ kan to wa ni ilu Kaduna lawọn gende agbebọn kan ti yinbọn mọ lasiko to wa si orilẹede Naijiria lati lo isinmi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi akọroyin BBC ti salaye, ọmọ ẹgbẹ alaanu kan, Mercy Corps, ni oloogbe ọmọ ilẹ Gẹẹsi ọhun, ti ko si ti si ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ kankan to tii kede pe oun ni oun wa nidi isẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi ileesẹ asoju ijọba ilẹ Gẹẹsi to wa ni Naijiria ti kede rẹ, ẹlomiran ti wọn tun yinbọn mọ ni Matthew Oguche, ẹni to n sisẹ fun ẹgbẹ alaabo kan ti kii se tijọba, ti wọn pe ni Safety Organisation.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

Sugbọn awọn ọlọpa ilẹ wa ni n se lawọn agbebọn naa n yinbọn soke laibikitalasiko ti wọn gbẹmi awọn eeyan mejeeji ọhun.

Iroyin naa ni iwa ijinigbe ti wọpọ pupọ ni ọpọ agbegbe lorilẹede Naijiria, to fi mọ ipinlẹ Kaduna, tawọn ajinigbe yii si maa n foju sun awọn ọmọ Naijiria ati awọn ajeji lati ji wọn gbe gba owo.