Child Trafficking: Ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá tẹ èèyàn 5 lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Osisẹ ọlọpa kan

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ọkunrin kan, Amanze Anyanwu ati iyawo rẹ Chinonye Oparaocha ẹni ọdun mẹtalelogun, ti ta ọmọ wọn tuntun jojolo, ti ko tii ju ọmọ wakati mẹfa lọ ni owo to to ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹrin o din mẹwa naira (₦850,000).

Gẹgẹ bi Kọmisọna ọlọpa nipinlẹ Imo, Rabiu Ladodo ti kede rẹ lasiko to n fi oju awọn afurasi ọhun han, salaye pe,iya ọmọ tuntun naa lo gbimọ pọ pẹlu awọn eeyan miran nibi to ti bi ọmọ tuntun ọhun lati ta ọmọ rẹ fun awọn eeyan kan ni ipinlẹ Rivers.

Ladodo ni lọjọ Kẹjọ osu Keji ọdun 2019 ti obinrin naa bimọ nile iwosan kan lopopona Nekede nilu Owerri, ni wọn gbe ọmọ wakati mẹfa ọhun lọ si ilu Portharcourt nipinlẹ Rivers, ti wọn si ta fun Duru Christian, ẹni to ti mura silẹ lati gba ọmọ naa, to si gbe fun ọkunrin kan ti wọn pe ni George Iyowuna.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Iyowuna yii ni iroyin naa ni o gbe ọmọ ohun fun ẹni to fẹ ra, William Cynthia ati ọkọ rẹ, ti wọn si san ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹrin o din mẹwa naira (₦850,000) fun.

Kọmisana ọlọpa naa ni lọjọ Kẹtala osu Kẹrin ọdun 2019 ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ileesẹ ọlọpa naa, lẹyin isẹ iwadi wọn to jinlẹ, gba awọn afurasi afọmọ sowo naa mu, to fi mọ iya ọmọ tuntun naa ati Nọọsi to gbẹbi fun.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

Ladodo, lasiko to n sapejuwe isẹlẹ yii bii eyi to ya ni lẹnu to si n ba ni ninujẹ, tun salaye pe marun ninu awọn afurasi ọhun ti ọwọ tẹ, ti n ka boroboro fun awọn ọlọpa nipa isẹlẹ naa, ti aayan si ti n lọ lati mu awọn afurasi yoku ti wọn ti na papa bora, to fi mọ baba ọmọ tuntun naa.

O fikun pe laipẹ ni wọn yoo gbe awọn afurasi naa lọ sile ẹjọ.