DR Congo Park: Olùdarí ìbùdó náà ní wọ́n ń fi fọ́tò yíyà sín olùtọ́jú wọn jẹ ni

Ẹnikan to n ya to pẹlu inaki meji

Oríṣun àwòrán, Ranger Mathieu Shamavu

Inaki nla meji to wa ni ibudo igbafẹ nla kan, Virunga National Park, ni orilẹede DR Congo, lo fẹran lati maa ya aworan adaya, ti wọn yoo si duro bii eeyan ninu fọto ti awọn olugbafẹ to ba wa sibẹ ya.

Awọn inaki naa, ni wọ̀n n tọ̀ju nibudo igbafẹ yii lẹyin ti ẹranko buruku kan awọn obi wọn..

Gẹgẹ bi igbakeji oludari ibudo naa ti sọ fun BBC, awọn inaki naa ni wọn kọ lati maa sin awọn eeyan to n tọju wọn jẹ, lati igba ti wọn ti ri wọn he, ti wọn yoo si duro bii eeyan lati ya fọto.

Àwọn ìròyìn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

O fikun pe awọn inaki naa ni wọn n ri awọn olutọju ibudo naa to wa layika wọn bii obi wọn ti wọn sekupa lọdun 2007

Ọdun meji ati osu mẹrin si lawọn inaki mejeeji ọhun lasiko ti wọn padanu obi wọn, idi si ree ti wọn fi ko wọn lọ si ibudo ti wọn n gbe ọhun.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

Innocent Mburanumwe, tii se igbakeji oludari ibudo igbafẹ naa ni "awọ̀n inaki yii n sin eeyan adarihunrun jẹ ni, ti wọn yoo si duro lori ẹsẹ wọn mejeeji bii eeyan lati yan fọto, bẹẹ ni wọn yoo gan pa.