Ìkọlu Ifọ: Ọlọ́pàá pòórá lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú yọ àdá sí wọn,

àwọn ọkọ ti awọn janduku jo nina ni ọga Kunle Oluomo ni Ifo, Ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun State/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Àwọn janduku naa lọ fi ibinu sọ ina si ọgba Kunle Oluọmó

Awuyewuye ti bẹ silẹ ni Ifọ ni Ipinlẹ Ogun bi awọn ọlọpaa ṣe yinbọn pa ọkunrin kan ti wọn funra si pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.

Awọn ọdọ to jẹ akẹgbẹ oloogbe naa ti fi ibinu lọ ile oloṣelu kan ti orukọ rẹ njẹ Kunle Oluọmọ, ti wọn si jo awọn ọkọ nla ati ile to wa nibẹ.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi, o ṣalaye wipe, ikọ ọlọpaa mu ọmọkunrin kan ti wọn funra si wipe, ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.

O ni nigba ti wọn si fi ọrọ wa lẹnu wo, o jẹwọ wipe awọn akẹgbẹ oun wa ni Ifo.

Oyeyemi sọ wipe, "Afurasi naa tẹle wọn lọ Ifo, wọn si gbe akẹgbẹ rẹ naa, ti wọn si gba awọn ibọn ati ọta lọwọ rẹ.

"Wọn n pada si Abeokuta ni awọn akẹgbẹ awọn afurasi mejeeji ba ṣe ikọlu si wọn lọna. Inu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn janduku ti fara gbọta.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

"Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ọkan lara awọn ọlọpaa ti o wa nibẹ ti di awati, a ko mọ oun to ṣẹlẹ si."

Oyeyemi àwọn janduku naa lọ wa kun ara wọn ti wọn si lọ ile oloṣelu ti wọn pe orukọ rẹ ni Oluọmọ lati lọ sọ ina si.