Micheal Jackson Vs Beyonce: Àwọn èèyàn sọ ẹní tó jẹ ọgá láàrín olórin méjèèjì

Aworan Beyonce ati Micheal Jackson

Ki a ma ṣebi ẹni pe a ko ri ohun tawọn eeyan n sọ lori ayelujara lori ọrọ to n ja rain rain pe, taa lọga laarin oloogbe Micheal Jackson ati Beyonce, lo mu wa fi ibeere sita.

Esi ti awọn eeyan fọ si ọrọ yii loju opo Facebook wa kọja afẹnusọ.

Bi a ba ni ki a ka ni meni meji, oju iwe yoo kun koda, yoo tun ṣeku.

Fun ẹyin ti ẹ ko ba ti laanfaani lati dasi, boya ki ẹ ka diẹ lara ohun ti wọn n sọ ki ẹ to mọ iha ti ẹ o kọ si ọrọ yi.

Amọ saaju, ki a to bẹrẹ akojọ ọrọ wọn yi, a fẹ ki ẹ mọ wi pe ohun gbogbo ti ẹ ba ka, awa kọ la sọ, awọn ololufẹ Micheal Jackson ati Beyonce ni wọn n sọrọ.

Ṣe Micheal Jackson a tun ma jẹ Mukaila Ajasin?

Ki a ti ibi ibeere yi bẹrẹ nitori orukọ ti arakunrin kan Mo'Sopaiqu Odedeyi pe Micheal Jackson niyi, nigba to n fesi si ariyanjinyan naa.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

Ninu ọrọ rẹ, ko ti lẹ ro wi pe olorin kankan le ba Micheal Jackson táákà rara.

Itz Yemi Abiola Black fẹran esi yi debi wi pe ohun naa pa ''suna'' orukọ miran fun Micheal Jackson, ti o si sọ ni orukọ ''Mukaila Sẹnwẹlẹ''

A ko mọ daju ẹni to da ọrọ naa silẹ ṣugbọn ninu awọn esi to wa loju opo BBC Yoruba Facebook, ko fẹ si ẹni ti o gbe lẹyin Beyonce, pe o ga ju Michael Jackson lọ.

Ki o ma dabi ẹni wi pe a n ṣe oju saaju, a kaakiri oju opo ayelujara lati wa ẹni to fara mọ pe Beyonce ju Micheal Jackson lọ.

Loju opo facebook BBC Pidgin lati ṣe alabapade ọrọ arakunrin kan Al Hassan III to sọ pe, Beyonce wa ni ipo kini ti Bob Marley tele ki o to wa kan Micheal Jackson.

Ko ti sọrọ naa tan ti awọn eeyan bẹrẹ si ni fun ni esi pada

Ọrọ naa ṣi n ja rain-rain ti ko si ti si ni to mọ ibi ti yoo kangun si.