Dagrin: Òní ló pé ọdún mẹ́sán án ti Dagrin dágbére fún ayé

Aworan Dagrin

Oríṣun àwòrán, @RayceRollin

Akọgun, Omo Ogun, Lyrical werey, Okunrin Ogun...diẹ lara awọn inagijẹ ti awọn ololufẹ Dagrin mọ ọ si re e .

Nigba to wa laye,o ko ipa ribiribi lagbo orin 'Rap' pẹlu bi o ti ṣe n fi ede abinibi rẹ,Yoruba da awọn eeyan lara ya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oni lo pe pe ọdun mẹsan an geerege ti ilumọọka olorin Rap nii, Olaitan Oladapo Olaonipekun 'Dagrin', ti wọn tun mọ si ‘Chief Executive Omo-Ita’ jade laye.

Loju opo Twitter, awọn ẹbi rẹ, ara ati ọrẹ ko ye se idaro rẹ, ti awọn kan si n beere wipe ṣe ki ṣe pe aye ti gbagbe ilumọọka akọrin yii?

Oríṣun àwòrán, @semasir

Dj Jimmy Jatt wa lara awọn to daro rẹ loni:

K- Solo ni orin Dagrin ma n dabi ọtun leti oun nigbakigba ti oun ba ti gbọ.

Olowo Igbalode se afiwe Dagrin pẹlu 2pac Shakur ọmọ ilẹ Amerika, ti oun na ku lewe, to si ni ki ẹlẹda dẹ ilẹ fun Dagrin.

Hushpuppi naa ko gbẹyin ninu iranti Dagrin. Koda o kede pe oun yoo fun awọn eeyan lẹbun owo ni iranti rẹ.

Lọjọ Kejilelogun Oṣu Kẹrin ọdun 2010 ni Dagrin padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ nilu Eko.

Àkọlé fídíò,

9ice: Ǹjẹ́ olórin tàkasúfèé yìí ń mu igbó bí àwọn òṣèré mìíràn?

Saaju ki awọn olorin bi Olamide ati Whizkid to di ilumọka, ni Dagrin ti n dagboro ru pẹlu Rap rẹ, to n fi ede abinibi Yoruba kọ.

Ọmọ ọdun mejilelogun ni, nigba ti o dagbere faye.