Irokotọla: Báwo ló ṣe rọrùn láti fi àmì sí ọ̀rọ̀ yìí, ‘Irokotọla’?

Irokotọla: Báwo ló ṣe rọrùn láti fi àmì sí ọ̀rọ̀ yìí, ‘Irokotọla’?

Asa fifi ami si ori ọrọ ti n lọ si okun igbagbe nilẹ Yoruba, paapaa laarin awọn ọdọ wa lode iwoyi.

Idi niyi ti ileesẹ BBC Yoruba se n tiraka lati mase jẹ ki asa naa parun nitori ede Yoruba jẹ ede to ni iro ọrọ.

Ninu aayan wa lọsẹ yii lati mọ bi awọn ọmọ Kaarọ Oojire ti gbọ Yoruba si, a ni ki wọn fi ami si ori iro ọrọ ‘Irokotọla', sugbọn ẹnu ko gba iroyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹtahoro pere si ni awọn eeyan to mọ irufẹ ami to wa lori ọrọ naa, nigba ti awọn eeyan miran sọ di ẹrin keekee.

Pabambari rẹ ni ti awọn ọmọ OOdua kan to tun n fi ede oyinbo fi ami si ori ọrọ yii, Kayeefi.

O ya, ẹ jẹ ka sere ọwọ, bawo lẹyin se gbọ Yoruba si, ẹ fi ami si ori irokotọla.