Ọọni: Ilẹ̀ ifẹ̀ ní ìran Ìgbò tí ṣẹ wá kìí ṣe ilẹ̀ juu

Ooni ife

Oríṣun àwòrán, Yera Moses Olafare

Onimọ kan nipa igbe aye ati ihuwasi awọn eeyan aye atijọ to fi fasiti UNN Nsukka ṣe ibujoko sọ pe o ṣeeṣe ki iran Igbo ṣẹ wa lati Ile Ifẹ ni ilẹ Yoruba.

Ojọgbọn Chidi Ugwu fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwọ pẹlu BBC ni idahun si ọrọ ti Ooni Ifẹ Oba Enitan Ogunwusi Adeyeye sọ laipe yi pe ọkan naa ni ẹya Yoruba ati Igbo.

Àkọlé fídíò,

Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

Oba Adeyeye nigba ti o n ba awọn ọmọ ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo kan to ba lalejo laafin rẹ sọ pe Ile Ifẹ ni orisun Igbo ati pe ibaṣepo laarin awọn ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

''A ni lati sọ ododo fun ara wa. Ọmọ iya kan naa ni wa. Ko yẹ ki nnkankan ya wa . Mo fẹ ki ẹ ri ibi gẹgẹ bi ile yin ki ẹ si bọwọ fun awọn ọmọ iya yin to jẹ Yoruba''

Oríṣun àwòrán, CHIEF SUNDAY JUDE IYOKE

Ninu alaye rẹ lori ọrọ naa, Ọjọgbọn Chidi ni ẹri jẹmi pe iran Igbo ṣẹ́ wa lati ile Ifẹ jẹyọ ninu orukọ awọn nnkan nilẹ Yoruba.

O mu apẹrẹ ọrọ bi Ifa lede Yoruba ati Afa ni ede Igbo, Atọ ati ẹta, owu ti awọn ẹya mejeeji jijọ n lo lati sapèjuwe owu iranṣọ ati ori jijẹ ti awọn mejeeji jọ n lo ọrọ kanna fun.

Àkọlé fídíò,

Ẹ wo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil tó wá síilẹ̀ Yorùbá láti mọ orisun wọn

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ miran to tun tọka si ni gbolohun Igbo eleyi ti Ọọni sọ pe o ṣẹ wa lati igba ti awọn Igbowa ni Ile Ifẹ.

''Loni, awọn Yoruba a ma lo ''Igbo'' ninu orukọ awọn ilu wọn ti eleyi si jẹ atọka pe ọrọ na jẹ ayalo lati igba ti awọn iran Igbo wa ni ile Ifẹ''

Apẹrẹ kan ti a ri fun alaye to sọ yi ti Ọọni na fidi rẹ mulẹ ni orukọ ilu Olugbo ti olori rẹ́ si n jẹ Akarigbo.

Gẹgẹ bi alaye Ọọni,lati Ile Ifẹ ni awọn Igbo to lọ tẹdo si Olugbo ti kuro ti itan si fihan pe awọn ni wọn pada wa n damu Ile Ifẹ.

Amọ ọba alayeluwa naa ni oun rọ awọn Ndigbo lati sọ fun awọn Igbo to ku pe wọn ko ṣẹ wa lati ilẹ Juu bi kii ṣe pe Ile Ifẹ ni orisun wọn.