Abẹ́rẹ́ àjẹsára àkọ́kọ́ tó n dènà ibà yóò dì mímú lò ní Malawi

Aworan iya ti o n gba abẹrẹ fun ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, D Poland/PATH

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti saaju dan iṣẹ abẹrẹ yi wo lara awọn eeyan ti o si ṣiṣẹ daada

Iṣẹ ibẹrẹ lori pipese abẹrẹ ajẹsara eleyi ti yoo daabo bo awọn ọmọde lọwọ airun iba ti bẹrẹ lorileede Malawi.

Abẹrẹ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni RTS, S ma kọ awọn ọmọ ogun inu ẹjẹ bi wọn yoo ṣe doju ija kọ kokoro aarun iba ti awọn ẹfọn ma n gbe kaakiri.

Saaju awọn ayẹwo diẹ diẹ kan fi han pe ida ogoji ninu ida ọgọrun awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ju osu marun un si mẹtadinlogun ni abẹrẹ naa n da aabo bo.

O jọ bi ẹni pe itankalẹ aarun iba tun ti fẹ ma gbori lyin bi ọdun mẹwa ti awọn oṣiṣẹ ilera bori aarun yi.

Dokita Kate O'Brien to jẹ adari eto gbigba ati pipese abẹrẹ ajẹsara ni ajọ WHO sọ fun BBC pe "Iṣẹlẹ manigbagbe ni eyi jẹ fun abẹrẹ ajẹsara,kikoju aarun iba ati ilera ara ilu''

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka iye awọn ti aarun iba n ba finra n peleke si juti tẹlẹ lọ-eyi ti mu ki awọn alaṣẹ́ ma jaya lori ọrọ naa.

 Anopheles mosquito.
SPL
Malaria in 2017

  • 435,000 died of malaria worldwide

  • 219m infectedAfrica saw more than 90% of cases and deaths

Source: WHO

Malawi in orileede akọkọ ninu awọn mẹta ti wọn yoo ti bẹrẹ lilo abẹrẹ ajsara yi .

Afojusun wọn ni pe ki ọmọ to to ẹgbẹrun lọna ọgọfa ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun meji lọ je anfaani rẹ. Awọn orileede meji to ku.

Ghana ati Kenya yoo bẹrẹ si ni fun awọn eeyan labẹrẹ naa lẹyin ọsẹ meji.

Wọn ṣa awọn orileede wọn yi lẹṣa to ri pe wọn ni eto ti wọn ṣe lati koju iba to fi mọ lilo awọn ṣugbọn iye eeyan ti iba n damu yi pọ nilẹ wọn

Bawo ni ipenija yi ṣe pọ to?

Lọdọọdun ni aarun iba ma n pa eeyan to to ẹgbẹrun lọna irinwo le marundinlogoji ti ọpọ wọn si jẹ ọmọde.

Gẹg bi ohun ti ajọ WHO sọ, pupọ awọn ti iba n pa wa l'Afrika nibi ti ọmọde to le ni ẹgbẹrun lọna òjìlénígba lé mewaa ma n ku.

Dokita O'Brien sọ pe ''iba jẹ aarun to ṣoro lati pese abẹrẹ ajẹsara ti yoo koju rẹ'' said that malaria is "a really difficult disease to develop a vaccine against".

Ipa wo ni abẹrẹ yi yoo mu wa?

O ti lẹ ni ọgbọn ọdun ti wọn ti n ṣiṣẹ lori ti awọn onimọ sayẹnsi lati ile iṣẹ ipoogun GSK bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.

Lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ti n ṣiṣẹ lori rẹ o ti tobi biliọnu dọla kan ti wọn ti na lori rẹ bayi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eeyan ti n pe fun ọna to daju lati koju aarun iba

Dokita Schellenberg ni ''Ko si ẹni to sọ pe ajẹbi idan ni abẹrẹ yi ṣugbọn yoo ni ipa ti yoo ko lati kojuaarun iba''

Ẹmẹrin ni wọn yoo fun eeyan labẹr yi,ẹmẹta laarin oṣu ti ẹni naa yoo si gba ikẹrin loṣu mẹjidinlogun lyin igba naa.

Wọn ni ireti pe wnyoo pari idanwolilo abẹrẹ yi lọdun 2023.