Àbẹ̀wò Buhari sí Eko: Àwọn ọ̀nà láti yàgò fún àyàfi tí ẹ ba gbé ibùsùn dání

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe abẹwo si Ipinlẹ Eko ni Ọjọru lati ṣi awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba Ipinlẹ Eko ṣe labẹ iṣakoso Gomina Akinwunmi Ambode.

Nitori naa ni ajọ ti o n moju to irinna ni ipinlẹ naa (LASTMA) ṣe fi atẹjade sita lori awọn ọna ti aarẹ yoo fẹsẹ tẹ.

Nigbakugba ti aarẹ ba ti wa si ilu Eko, iya maa n jẹ awọn olugbe ilu Eko ni atari sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ. Eyi lo jẹ ki ajọ LASTMA fi to awọn olugbe ipinlẹ naa leti awọn ọna ti irin aarẹ yoo de.

Awọn ọna wọnyii ni aarẹ yoo foju ba laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan ree:

1. Mobolaji Anthony Way (Lati papakọ ofurufu Murtala Mohammed si abẹ afara to wa niwaju ile iwosan LASUTH)

2. Ọna Kodesoh

3. Obafemi Awolowo Way

4. Kudirat Abiola Way

5. Popona Ikorodu (Laarin ọjọta si iyana Anthony)

6. Popona Owonronshoki si Apapa (Laarin Anthony si Oshodi

7. Ọna papakọ ofurufu

LASTMA ti ni awọn ọna wọnyii yoo wa ni titi nigba ti aarẹ ba n kọja tabi to ba duro lati ṣi iṣẹ akanṣe.

Ajọ naa si tun ti rọ awọn olugbe Ipinlẹ Eko ki wọn yago fun awọn ọna wọnyii.

Àwọn ìròyìn tì ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àkọlé fídíò,

Wo ohun tí ọkùnrin yìí ń sọ táyà ọkọ̀ dà