Osoba: Àwọn tó ń bèèrè fún àtúntò ń jà fún ikùn ara wọn ni

ATUNTO

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olusegun osoba wà ní ara àwọn tó se àpérò lórí ìwé ìlànà àti òfin Naijiria ní ọdún 1976.

Arẹmọ Olusegun Osoba ti ni awọn ọmọ Naijiria nikan lo le gba ara wọn la lọwọ amunisin lorilẹede Naijiria.

Osoba so eyi lasiko to n fi lede wi pe ọrọ Naijiria ko nii se pẹlu atunto orilẹede, afi ki awọn Naijiria dide lati gba ara wọn.

Lasiko to n se ifilọlẹ iwe rẹ ti oun ati oloogbe Dokita Bala Usman kọ lori iwe ilana ofin Naijiria ti ọdun 1976, Osoba ni awọn to n pe fun atunto Naijiria n ja fun ikun ara wọn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olusegun Osoba, to wà lara àwọn tó se àpérò lórí ìwé ìlànà àti òfin Naijiria ní ọdún 1976 tun ni ‘Irọ patapata ni atunto Naijria, awọn ti wọn beere fun ko ni otitọ, wọn fẹ dari ohun alumọni orilẹede Naijiria ni.’

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

‘O yẹ ki igbe aye awọn ipinlẹ to n pese ohun alumọni epo rọbi dara ju bo se wa lọ, amọ awọn adari ipinlẹ naa n lo owo ilu basubasu nipa didari owo si ibi ti ko yẹ.’

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ igba ni awọn eniyan nla nla lawujọ ma n bere fun iyipada ofin ati ilana orilẹede Naijiria

Ọjọgbọn Olusegun Osoba wa fikun wi pe, ọna abayọ si isoro Naijiria ni ki awọn ọmọ Naijiria ma a fi ẹhọnu wọn han lati igba de igba.