Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Adiitu ni ọrọ Olodumare, ko si ẹni to lee ye, bo ba si se wu ni ẹlẹda se n se ọla.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun Ọgbẹni Bisi Alimi, tii se ọkan lara awọn isẹda eeyan kan, ti wọn ko nifẹ lati se igbeyawo pẹlu irufẹ isẹda wọn.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Bisi Alimi salaye pe, ọrọ akọ to n fẹ akọ, tabi abo to n fẹ abo ko nii ohunkohun se pẹlu ẹsin rara, isẹ ọwọ Olodumare ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni iya oun maa n sunkun pe oun ko pe lọmọ tabi pe oun ko lee ta putu, ni oun ko se ni ifẹ abo, sugbọn o ni eyi ko ri bẹẹ, bi Ọlọrun se se isẹda ti oun ni.

Bisi Alimi ni oun ti segbeyawo pẹlu ọkunrin miran ni ilu London, ti awọn si jọ n gbe papọ, nitori oun ko lee gbe obinrin ti oun ko ni ifẹ kankan si, sinu ile.

O wa rọ ijọba ilẹ Naijiria, awọn asofin, akọroyin ati awọn agbẹjọro lati se ofin ti yoo se ofin ti yoo tẹ gbogbo ọmọ Naijiria lọrun, ti ko si ni jẹ ofin ti yoo fa ori apa kan, da apa kan si.