Àbẹ̀wò Buhari: Mo fẹ́ kí òjò rọ̀ ní Eko, kó sì ba àbẹ̀wò Buhari jẹ́

Ara akanse isẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari fẹ si

Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe abẹwo si ilu Eko loni lati wa si awọn akanṣe iṣẹ kan tijọba ipinlẹ Eko ṣe.

Lara awọn akanṣe naa ni ibudo igbẹbi awọn oloyun ti wọn pe ni Ayinkẹ House to wa ni Ikẹja, Ibudo ere tiata to wa ni Ọrẹgun ati opopona olobiripo to wa ni Oshodi.

Awọn isẹ akanṣe yoku ni ọkọ bọọsi bọginni tuntun ati opopona tuntun to lọ si papakọ ofurufu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yoruba ni iroyin ko to afojuba lo mu ki BBC fẹsẹ kan de awọn ibudo tawọn akanṣe iṣẹ naa wa, ta si ri pe lootọ iṣẹ ko ti pari lori awọn isẹ naa rara.

Koda ijọba ipinlẹ Eko gan ti kede fawọn araalu lati mọ awọn oju ọna ti wọn yoo ti pa ati awọn eyi ti ijọba yoo si fun lilo, eyi tawọn araalu ni yoo tubọ dakun sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni Eko lasiko abẹwo aarẹ naa ni.

Awọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye ti kun pitimu nipa ero araalu lori abẹwo aarẹ Muhammadu Buhari si ilu Eko.

Niwọn igba to si jẹ pe bakan meji ni ẹnu ọmọ araye, bi awọn eeyan kan se n foju sọna fun abẹwo naa, ni awọn eeyan kan n yinmu pe awọn isẹ wo gan ni Buhari n bọ wa si ni Eko.

Awọn eeyan kan tiẹ n gbarata lori inira ti abẹwo naa yoo mu bawọn nitori awọn opopona kan ti ijọba yoo ti pa lasiko abẹwo aarẹ Buhari naa.

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Lero tawọn eeyan kan, wọn gbe si oju opo Twitter wọn pe ọpọ isẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari n bọ wa si naa ni isẹ ko tii pari lori wọn, amọ ti gomina Akinwunmi Ambọde fẹ fi iwanwara si awọn isẹ naa.

Loju opo Adetayo Adeseyi, @ade_tayos, o ni oun lero pe ojo yoo rọ loni lati ba abẹwo Buhari jẹ ni Eko.

Ubong Ekpo lero tiẹ ni se ko seese ki wọn pari awọn akanse isẹ naa ki Buhari to wa si Eko ni, paapa opopona to lọ si papakọ ofurufu to wa ni Oshodi. O ni ẹru n ba oun pe wọn yoo sọ opopona ọhun di akọpati ni lẹyin ti Buhari ba ti si tan gẹgẹ bi wọn ti se ni ibudokọ to wa ni Ikẹja.

Cece @Folasade_h sọ loju opo rẹ pe ko si ẹni ti inu rẹ dun si abẹwo aarẹ naa ju iya oun lọ, ti oun ko si mọ idi ti inu rẹ fi dun.

Nicholas Ibekwe lero tiẹ lori Twitter, @nicholasibekwe salaye pe gẹgẹ bi ise rẹ, Buhari tun n bọ ni Eko lati wa si awọn akanse isẹ ti ko tii pari rara.