Ondo Police: À ń wá Deji Adenuga tó dáná sun ènìyàn mẹ́jọ

Ile to jona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọmọkunrin kan dana sun mọlẹbi ọrẹbinrin rẹ nigba kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Fẹmi Joseph sọ fun BBC Yoruba pe, ọdọmọkunrin naa, Deji Adenuga ti awọn eniyan tun mọ si Dakar, ni wọn fura si pe o dana sun mọlẹbi naa ni ilu Igbodigo, nijọba ibilẹ Okitipupa l'oru ọjọ Aiku mọju ọjọ Aje, laarin aago meji si mẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Joseph sọ pe ọmọkunrin naa n fẹ ọmọbinrin kan ninu ẹbi naa , Titi Saanu, ko to o di pe Titi ja okun ifẹ naa pe oun ko ṣe mọ.

Eyi lo si mu ki Deji fi ibinu lọ dana sun ẹbi Titi mọle.

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

'Nibayi, eniyan mẹjọ ti ku ninu ẹbi naa, nitori bi ina ṣe jo wọn. Titi funra rẹ n bẹ ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nileewosan.

Ọgbẹni Joseph sọ pe lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye, ni Deji ti sa kuro niluu, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti n wa.