NCC: Á gbógun ti àwọn èèyàn tí kò bá fi orúkọ nọ́mbà ìpè wọn sílẹ̀

Awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ

Oríṣun àwòrán, @NgComCommission

Ajọ to n bojuto awọn ileesẹ ẹrọ ibanisọrọ lorilẹede Naijiria, NCC, ti ni iwe ofin Naijiria to nii se pẹlu idabobo orilẹede,ni awọn yoo lo fi gbogun ti awọn ti ko ba se iforukọsilẹ 'Sim Card' wọn kaakiri orilẹede Naijiria.

Olori ẹka to n risi imusẹ ofin Ajọ NCC, Efosa Idehen ni oju opo ibaraẹnisọrọ Facebook ajọ naa sọ wi pe, ọpọlọpọ awọn jandugu lo n lo awọn 'Sim Card' ẹbu fun ijinigbe lati gba owo ẹmi.

Idehen ni o le ni miliọnulọna marundinlọgọjọ awọn ọmọ Naijiria to ti bẹrẹ iforukọsilẹ wọn, amọ ti idamẹta awọn nọmba wọnyii jẹ ẹbu nitori wọn ko pari iforukosilẹ naa tabi awọn ọrọ akọsilẹ wọn ko barajọ, eleyii to jẹ ko lufin ajọ NCC.

O rọ awọn ile isẹ imọ ẹrọ ibanisọrọ ati eyi to n se 'Sim Card lati fi aabo ilu saaju ohunkohun, ki wọn ba le ri wi pe `aabo awọn ara ilu jọ wọn loju, ki itẹsiwaju le ba orilẹede Naijiria.

Bakan naa, ajọ naa wa ke si awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma mikan nitori awọn ko ni fi ọrọ akọsilẹ wọn lede afi ti o ba niise pẹlu eto aabo lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Ajọ naa wa parọwa si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati ri wi pe wọn se ojuse wọn ki eto aabo orilẹede naa ma ba a mẹhẹ.

Tó bà á fi nọ́mbà ìpè rẹ sílẹ̀, ẹ̀wọn ọdún mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n lo fi ń ṣeré - NCC

Ajọ to n bojuto ẹrọ ibanisọrọ lorilẹede Naijiria, NCC, ti ni awọn ọmọ Naijiria ti wọn n lo ‘Sim Card’ ti ko ni iforukọsilẹ to miliọnu lọna ọgọrun.

Kọmisọnna fajọ NCC, Sunday Dare lo fi ọrọ naa lede ni ilu Port Harcourt lasiko to n se ilanilọyẹ fun awọn eniyan ni agbeegbe naa.

Dare ni ‘Sim Card’ awọn eniyan miran di ofutufẹtẹ nitori wọn ko tẹ ika wọn daradara soju ẹrọ ti wọn fi se iforukọsilẹ, ati wi pe wọn ko fi aworan wọn si ibẹ daradara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni lara ijamba ti iforukọsilẹ ni wi pe eniyan to ba jẹbi ẹsun naa le fi ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn jura lori ẹsun pe o pa irọ orukọ rẹ labẹ ofin.

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Ajọ naa wa fikun wi pe awọn yoo bẹrẹ si ni da awọn eniyan pada si gbogbo ibudoko ti wọn yoo ti lo tun iforukọsilẹ naa se.