Owó làwọn olóṣèlú mọ̀ ni wọ́n ṣe fẹ́ kí dókítà lọ sókè òkun - NMA

Awọn dokita to wọ asọ funfun

Oríṣun àwòrán, @Gebrekiros

Ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria, NMA ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti minisita fọrọ isẹ, Chris Ngige sọ wi pe, awọn dokita pọ yanturu lorilẹede Naijrria, nitorina aaye si silẹ fun awọn dokita to ba fẹ kuro nilẹ yii lọ si oke okun.

Aarẹ ẹgbẹ awọn Dokita, Dokita Adedayo Faduyile lasiko to ba BBC sọro ni, awọn dokita ko to ni Naijiria nitori wi pe dokita kan lo n tọju si ẹgbẹta eniyan lo yẹ kojẹ , amọ o le ni ẹgbẹwa eniyan to n lo dokita kan.

Faduyile ni owo ni awọn oloselu mọ ni wọn se n faramọ ki awọn dokita ma a lọ si oke okun, amọ o ni ohun to buru ni ki awọn eniyan ma ni eto ẹkọ to peye lorilẹede naa.

Àkọlé fídíò,

Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

O parọwa si ijọba lati jẹ ki ilera awọn ọmọ orilẹede naa jẹ awọn ijọba loju, ki wọn si se ohun to to lati ri wi pe awọn ọmọ Naijiria jẹ anfaani eto ilera to peleke.

Bẹẹ ba gbagbe, minisita fọrọ osisẹ, Chris Ngige lo ti sọ saaju pe awọn dokita ti pọ ju lorilẹede Naijiria, eyi to ba si wu ninu wọn lee kọri si oke okun lati wa isẹ aje lọ.

Oríṣun àwòrán, WHO

Ngige, ẹni to sisọ loju ọrọ̀ yii lasiko to n opa lori eto kan lori mohunmaworan tun fikun pe, ko si ohun to buru ninu kawọn dokita yii ko aasa wọn lọ si oke okun niwọn igba ti wọn yoo maa fi owo ilẹ okeere ransẹ sile.