Ido-Ani Robbery: Àhámọ́ làwọn afurasí náà yóò wà di ọjọ́ Kejì oṣù Karùn-ún

Aworan awọn ọlọpaa to gbe adigunjale si inu ọkọ
Àkọlé àwòrán,

Awọn maarun lo foju ba ile ẹjọ ti ẹnikẹfa wọn to ku ti na papa bora

Ile ẹjọ magistireti to wa nilu Akure ti paṣẹ ki wọn ti awọn adijunjale mẹfa, ti wọn funra si pe wọn kopa ninu ikọlu ile ifowopamọ kan ni Idoani si ahamọ.

Ni nnkan bi oṣẹ meji sẹyin ni wọn mu wọn lori ẹsun pe wọn kopa ninu idigunjale bankii naa nibi ti eeyan meje ti padanu ẹmi wọn.

Adajọ Victoria Bob Manuel to paṣẹ yii ṣe bẹẹ lẹyin atotonu lati ọdọ awọn agbẹjọro ijọba ati tawọn afunrasi naa.

Àkọlé fídíò,

Offa Robbery: Àwọn aráàlú ṣi n gbé nínú ìpaya lẹ́yìn ọdún kan

Ninu idajọ rẹ, o ni ki wọn fi awọn adigunjale naa si ahamọ titi di ọjọ keji oṣu Karun un titi di igba ti adari ẹka olupẹjọ yoo fi gbawọn ni imọran to yẹlori ẹjọ naa.

Awọn ọlọpaa ti fi ọkọ wọn gbe awọn afunrasi naa pada si ahamọ.

Maarun un ninu awọn adigunjale naa lo yọju siwaju adajọ lati jẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ẹnikẹfa wọn la gbọ pe o ti na papa bora.

Oríṣun àwòrán, Thenationonline

Àkọlé àwòrán,

Wọn fi agidi mu awọn oṣiṣẹ ileefowopamọ lati ṣi ilẹkun rẹ, ṣugbọn owo ti wọn ba nibẹ ko jọ wọn loju rara.

Bi a ko ba gbagbe, awọn adigunjale naa ko ibọn ati awọn ohun ija oloro miran lọwọ, ti wọn si yabo ile ifowopamọ First Bank to wa ni Idoani lọjọ Kẹjọ osu Kerin ọdun 2019.

Nigba ti wọn yoo fi pari iṣẹ aburu wọn, ẹmi meje lo ba iṣẹlẹ naa lọ.