Man Utd Vs Man City: Kò ṣèlẹ́rí! àwọn alatilẹyin Liverpool yóò gbè lẹyìn Man Utd

Aworan alatilẹyin to mu ami Liverpool ati Man City lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lalẹ oni, nkan ti ko fẹ ṣẹlẹri lagbo ere boolu Premiership yoo ṣẹlẹ.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United yoo gbe lẹyin Manchester City ti awọn ti Liverpool yoo si ma gbadura ki Manchester United fẹnu Man City gbole.

Ọrọ naa ri bakan abi? Bẹẹni awa na ti ṣe ro amọ ifẹsẹwọnse ti yoo waye lale oni lo mu ki orẹ di ọta ki ọta si di ọrẹ.

Lori afara liigi Premiership, ọrọ ipo kini ti di fa-kinfa laarin ẹgbẹ Manchester City ati Liverpool ti esi ifẹsẹwọnsẹ laarin Man United ati Man City lalẹ oni yoo si jẹ atọna ẹni ti yoo gba liigi ọdun yi.

Lọwọlọwọ, ami ayo kan ni Liverpool fi n lewaju Manchester City ti o si jẹ wi pe ti Man City ba fi le bori Man United, awọn ni yoo di ipo kini mu saaju Liverpool.

Ti Man City ba fidi rẹmi lọwọ Man U, Liverpool yoo sunmọ ki wọn gba liigi, eyi ko si jẹ nkan ti awọn alatilẹyin Man U faramọ.

Kaka ki Liverpool gba liigi, wọn ko ni kọ ki Man City gba amọ ki eleyi to le ṣẹlẹ wọn yoo fara gba idojuti ki Man City bori wọn.

Hmmm ọrọ naa buso si ni lẹnu to tun bu yọ si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo fa ọta laarin Manchester United ati Liverpool ?

Ọjọ ti pe ti ọta awọn mejeeji ti bẹrẹ ṣugbọn lnu igba ti liigi Premiership di ilumọka yi, awọn alatilyin wọn ko fẹ ri imi ara wọn lakitan.

Kii ṣe Liverpool nikan ni Manchester United ko nifẹ. Man City ti wọn jijọ wa nilu kanna kii ṣe ẹni ti wọn jijọ n fẹyin si ara wọn.

Loju opo Twitter kaakiri, ero ọkan awọn alatilẹyin ẹgbẹ mẹtẹta, Man U, Liverpool ati Man City a ma farapera ti wọn a si tun ma yapa si ara wọn

Laago mẹjọ alẹ oni ni gbangba yoo dẹkun ti kedere yoo bẹẹ wo.

Bi Manchester United ni yoo bori ni bii Man City ni, ipade di ori papa.