Child marriage: $3,500 la gbà láti fa ọmọ ọdún márùn-ún f'ọ́kọ

Omobinrin Image copyright iSok
Àkọlé àwòrán Omobinrin

Ọdun marun ni Nazanin ti ni ọrẹkunrin ti yoo fẹ. Nigba ti yoo si fi pe ọdun mẹwaa, o ti di iyawo lọọdẹ ọkọ. Idile ọkọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mejila ra a ni $3,500 ni dun mẹfa sẹyin.

Awọn obi rẹ ta a lati le kowo jọ fi tọju ọmọkunrin wn to wa ń ṣaisan iyẹn, aburo Nazanin.

"Irora yii pọ fun ọmọ mi ọkunrin. nigba ti mo wo oju rẹ, mo ro o wi pe ki a gba owo naa. Baba Nazanin kọkọ lra tikọ ṣugbọn emi ni mo mu ọkọ mi lọkan le pe ko gba owo naa lati ta ọmọ wa obinrin". Iya ọmọ naa lo sọ eyi, o n gbe ni ibudo awọn ti ko rile gbe ni Shahrak e Sabz lẹba Herat, iwọ oorun Afghanistan.

Ọmọ meje ni baba ati iya Nazanin bi - obinrin mẹta ati ọkunrin mẹrin. Wọn o lọ ile iwe rara debi ti wọn yoo mọ ọ kọ tabi mọ ọ ka. Ko s'owo ko si iṣẹ.

Akọroyin BBC, Yasini Inayatulhaq ba idile yii sọ̀rọ̀ lori ipinu wọn lati ta ọmọ wọn.

Baba ni "lati ọmọ ọdun mẹrin ni aisan warapa ti n yọ ọmọkunrin wa lẹnu a o si lowo fun itọju rẹ"

Nigba ti titiraka yii pọ lati doola mi ọmọkunrin wọn ni ẹbi gba lati ta ọmọbinrin wọn.

"Mo gba owo mo si fi ọmọ wa obinrin to dagba ju le ọkọ. Mo fi owo ọhun san owo itju ọmọ mi ọkunrin. Ṣugbọn aisan to n ṣee ko gbọ bẹẹ si ni mi o le gba ọmọ ti mo ta pada ni iya wi.

"Bi ẹnikẹni ba ta ọmọ rẹ ni ọna yii, o daju yoo kabamọ. Emi gan kabamọ sugbọn ko wulo mọ ni baba sọ.

Igbeyawo ọmọde

Ni orilẹede Afghan, ọdun ti ofin faaye gba ki ọmọ ṣe igbeyawo ni ọdun mẹrindinlogun fun ọmọbinrin ati mejidinlogun fun ọmọ ọkunrin. Ṣugbọn ọpọ lo ṣeyawo lai ti to awọn ọdun yii.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ Unicef ṣe sọ ọ, ida marundinlogoji ọmọbinrin Afghan lo ti maa wa nile ọk nigba ti wọn ba fi pe ọdun mejidinlogun, ida mẹsan wọn si lo ti ṣeyawo ki wn to pe ọdun mẹẹdogun.

Gbígbé nínú ìrètí

Lọwọ lọwọ, idunu jina si idile naa nitori wọn ni ko si ẹnikẹni lati ran wọn lọwọ. Eyi si n mu inu bi ọmọde ti wọn sọ di iyawo.

Iya rẹ ni, "Nazaninn sọ fun mi: Mama mi, ẹ ta mi lọmọde ṣugbọn ara ẹgbọn mi ko tii ya. O tun wa ni 'ṣugbọn ara aburo mi yoo ya emi naa yoo si dagba. 'Mo kabamọ pe mo fii fọkọ ṣugbọn mo ṣi ni ireti ọjọ ọla to dara". Eyi ni iya rẹ sọ.

(A pa orukọ Nazanin da ni lati le da abo bo o)

Related Topics