Mike Zhang dì ọmọ China akọkọ tí wọ́n f'oye dá lọla ní ìpínlẹ̀ Kano

Àkọlé fídíò,

Báyìí ni ayẹyẹ wíwé láwàní fún ọmọ China, olóyè Zhang ṣe lọ

A o ri iru eleyi ri, a fi dẹru ba ọlọrọ ni. Bi eeyan ba si rin jina, yoo ri abuke ọkẹrẹ.

Bi ọrọ naa ṣe ri re nilu Kano nigba ti arakunrin ọmọ orileede China kan di akọkọ ọmọ orileede rẹ ti wọn yoo fi jẹ oye nipinlẹ Kano.

Onisowo Mike Zhang to ti lo ọdun mẹtadinlogun ni Kano ni, niṣe ni inu oun dun pẹlu ọla ti wọn da oun yi.

O ni oun yoo ṣapa lati rii wi pe awọn ọmọ orileede China to wa ni Kano yoku pawọpọ lati ni ibaṣepọ to dara pẹlu awọn eeyan Kano.

Emir ilu Kano, Muhammad Sanusi ṣalaye pe idi ti oun fi fi oye da Zhang lọla ni pe o ni ipa rere laarin igba ti o lo ni ipinlẹ naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ China miran kọwọrin pẹlu rẹ nibi ayẹyẹ naa

O ni "Wakilin Yan China, mo ki ọ ku orire, o ti jẹwọ pe o ni ipa rere, mo si lero wi pe oye yii yoo mu ki o tẹramọ iṣe daada ti a mọ ọ si''

Ojojumọ ni iye ọmọ China to n ṣowo nipinlẹ Kano n pọ sii. Lẹka awọn oniṣowo aṣọ, to fi mọ tita oogun apakokoro ati bata , awọn ọmọ China ko gbẹyin.

Awọn kan ri oye yii gẹgẹ bi ohun to n tọka si ipa ti orileede China ni kaakiri ilẹ Afrika, ti awọn kan si n bẹru pe laipẹ China yoo gba akoso ọpọlọpọ ẹka mọ awọn eeyan Afrika lọwọ.

Àkọlé àwòrán,

Zhang ni oludasilẹ ile iṣẹ to n pese omi mumu

O le ni ẹgbẹrun marun un ọmọ orileede China to n gbe ni Kano.

Alaga awọn ile iṣe to n pese nkan nipinlẹ Kano, Umar Marshall ni oun idunnu ni oye yii nitori ko si awujọ ti o le ni itẹsiwaju lai fi tawọn ajoji ṣe.