Nigeria Police: Ọ̀gá àgbà dín wákàtí iṣẹ́ ọlọ́pàá kù 'torí wàhálà

Awọn ọlọpaa Image copyright Getty Images

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ pe ki adinku de ba iye wakati ti awọn ọlọpaa fi n ṣiṣẹ l'ojoojumọ.

Ọgbẹni Adamu to sọ ọrọ naa lasiko to n ṣi ipade ijiroro kan to waye laarin awọn ọga lawọn ileewosan ileeṣẹ ọlọpaa ni olu ileeṣẹ naa sọ pe ki adinku de ba a lati wakati mejila di mẹjọ.

Ọga agba ọlọpaa sọ pe igbesẹ naa waye nitori awọn ẹsun pe ọlọpaa ṣeeṣi yinbọn, pa araalu lọna ti ko ba ofin mu, nitori pe o ti rẹ wọn nitori wahala ti wọn ṣe l'ẹni iṣẹ, eyi to n ni ipa lara ihuwasi ati afojusun wọn.

Adamu ṣalaye pe ''ohun ti eyi tumọ si ni pe ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ wa ọna tuntun lati maa ṣe iṣẹ wọn, ati iru anfaani ti araalu n jẹ l'ara wọn ni gbogbo ọna ti awọn ọlọpaa n gba ṣe iṣẹ wọn.''

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí