Zainab Habib Arábìnrin wà ní àhámọ́ ní Saudi lórí ẹsùn tí kò mọ

Zainab Habib Image copyright Hajara Habib
Àkọlé àwòrán Aworan Zainab Habib

Awọn akẹkọ fasiti Yusuf Maitama Sule nilu Kano yoo ṣe iwọde lọjọ Iṣẹgun tori akẹgbẹ wọn kan Zainab Habib Aliyu ti wọn fẹsun gbigbe ogun oloro kan lorileede Saudi.

Oṣu Kejila ọdun 2018 ni awọn agbofinro nilẹ naa mu Zainab nigba ti o lọ ṣe Umrah. Wọn fẹsun kan pe o gbe oogun oloro.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn kan ni wọn fi oogun oloro naa sinu ẹru rẹ ati pe ko si mọ nipa rẹ titi ti wọn fi mu u ni Saudi.

Lati igba naa titi di bi a ti ṣe n sọrọ yii, Zainab to jẹ akẹkọ fasiti Yusuf Maitama Sule ṣi wa ni atimọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà

Bawo ni wọn ṣe mu u?

Zainab lọ si orileede Saudi lati lọ ṣe Umrah ṣugbọn ko rii ṣe nitori ọjọ to de ibẹ naa ni wọn mu u.

Nilu Madinah ni wọn ti mu Zainab niṣoju iya rẹ ati ọmọ iya rẹ ninu ile itura ti wọn de si.

Niṣe ni wọn wa si iyara wọn ti wọn si bẹrẹ si ni tu ẹru rẹ pe awọn ri ogun oloro ninu baagi rẹ tori naa o di dandan ko tẹle wọn.

Ọmọ iya rẹ Hajara to ba BBC sọrọ sọ pe ojojumọ lawọn n ba Zainab sọrọ.

''Nigba myi yoo ba ọkan jẹ, nigba mii ara rẹ yoo ya si wa ti a ba fun un ni iroyin bi ẹjọ rẹ ṣe n lọ si''

Image copyright Hajara Habib
Àkọlé àwòrán Zainab,,Iya rẹ ati ọmọ iya rẹ saaju ki wọn to mu

Awọn wọ lo ṣakoba fun Zainab?

Awọn alaṣẹ lorileede Naijiria sọ pe awọn ti mu eeyan meje to lọwọ ninu bi ogun oloro ṣe de inu ẹru Zainab.

Ajọ to n risi ọrọ to niṣe pẹlu gbigbogun ti lilo ogun oloro, NDLEA ṣe iwadii lori ọrọ Zainab ti wọn si ni ọwọ ti tẹ eeyan meje to n ṣiṣẹ ni papakọ ofurufu Aminu Kano.

Ẹwẹ, ijọba Naijiria ti tẹnu bọ ọrọ naa bayii.

Oluranlọwọ agba si Aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okere Abike Dabiri ni Aarẹ ti paṣẹ ki olugbẹjọ agba wa wọrọkọ fi ṣada ki wọn si rii wi pe o lojutu.

Orileede Saudi Arabia kii fi ọrọ gbigbe ogun oloro ṣere rara.

Idajọ iku ni wọn ma n da fun pupọ awọn ti ọwọ ba tẹ wi pe wọn gbe ogun oloro.

Awọn akẹkọ fasiti Yusuf Maitama Sule ni Kano to fẹ ṣe iwọde naa lero wi pe ijọba yoo gbe igbesẹ kiakia lori ọrọ Zainab ki o ba le pada wa sile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'