Ìbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

African Drum Festival: Ìbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà

Bẹẹ ba ti ri ogidi ọmọ ile onilu to mọ iṣẹ idile rẹ, wọn o ṣoro da mọ tori orukọ a maa ro wọn.

Bii ti Ayanfunkẹ ati Ayanronkẹ Ganiyu, oju ni wọn ni ilu ti wọn ti wa nitori lati igba ti wọn ti wa ni nkan bii ọmọ ọdun méjì ni gangan ti n dun ti bata naa si n ro kola kola lati ọwọ wọn.

Lati mọ iya ilu nikan gan gẹgẹ bi ọba ilu, kii ṣe iṣẹ kekere ṣugbọn ni ti Ayanfunke pẹlu ekeji rẹ, oriṣiriṣi ilu ni wọn lee dawọ le lai foya eyi ko si sẹyin baba wọn, Ọgbẹni Ganiyu ẹni to ti wa di alamojuto wọn ni gbogbo ode tabi eto ti wọn ba n lọ.