Zainab Habib tí wọ́n fẹ̀sùn òògùn olóró kàn gba ìtúsílẹ̀ ní Saudi

Zainab ati ikọ ijọba Naijiria Image copyright Ministry of Foreign Affairs
Àkọlé àwòrán Zainab ati awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ orilẹede Naijiria niluu Jeddah lẹyin ti wọn tu u silẹ l'ọgba ẹwọn.

Ijọba Naijiria ti kede pe wọn Zainab Habib Aliyu to wa ni ẹ̀wọ̀n l'orilẹede Saudi Arabia lori ẹsun gbigbe oogun oloro ti gba ominira.

Akọwe agba nileeṣẹ ijọba to wa fun ọ̀rọ̀ ilẹ okeere, Mustapha Suleiman lo kede iroyin naa sita nilu Abuja.

O ṣalaye pe nigba tijọba gbọ nipa bi wọn ṣe fi ọmọbinrin naa sẹwọn, ni ijọba bẹẹrẹ iwadii to tu aṣiri pe awọn ikọ oloogun oloro kan lo maa n fi ọgbọn gbe oogun oloro sinu ẹrù awọn eniyan to n lọ si Saudi Arabia.

Aṣiri to tun ọhun lo mu ki wọn o yọju si ọọfisi orilẹede Saudi to wa ni ilu Abuja lati bẹrẹ igbesẹ lori bi Zainab yoo ṣe gba ominria.

Awọn ẹ̀rí to wa nilẹ si lo mu ki awọn alaṣẹ Saudi tu ọmọbinrin naa silẹ.

Bí Zainab ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n Saudi lórí ẹ̀sùn ògùn olóró tí kò mọ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbejì Àyànbìnrin tó ti ń di gbajúgbajà

O ni ọmọbinrin naa ti wa pẹlu awọn alaṣẹ ọọfisi orilẹede Naijiria to wa ni Saudi Arabia.

Baba ọmọbinrin naa, Alhaji Habibi Aliyu sọ fun BBC pe awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe ọmọ oun ti gba ominira.

O ni botilẹjẹ wi pe oun ko ti i ba ọmọ oun sọrọ, ọkan oun balẹ bayii.

'Mo ṣẹṣẹ gba ipe naa tan ni, koda mi o le sọ bi inu mi ṣe dun to. Oni jẹ ọkan lara awọn ọjọ ti inu mi dun ju l'aye.

Bakan naa ni Alhaji Aliyu sọ pe nkan to ṣẹlẹ si ọmọ oun fihan pe ọpọ alaiṣẹ lo n jiya ẹsun ti wọn ko mọ nkankan nipa a rẹ.

Ẹwẹ, oluranlọwọ pataki fun aarẹ naa fi ikede itusilẹ rẹ sita loju opo Twitter rẹ.

Bakan naa, àwọn ọmọ Naijiria ti tú sí àwọn ojú òpó ayélujára láti bẹ̀rẹ̀ sí ni fi ọ̀pẹ́ fún ọlọ́run ti wọn si n gboriyin fun ijọba orilede Naijiria.