Oyo government: Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ Ìyálọ́jà àti Babalọja ń fà awuyewuye?

Aworan onisowo lọja Oshodi nilu Eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn obinrin niYoruba gba pe wọn jẹ alamojuto ọja ti wọn a si ma yan Iyalọja laarin wọn

Bi eeyan ba n gbe ni ilẹ Yoruba, ko jẹ kayeefi ti wọn bá darukọ Iyalọja tabi Iyalaje

Lati ijọ ti alaye ti daye ni ilẹ Yoruba ni wọn ti n yan awọn obinrin to kaju osunwọn lati di ipo náà mu.

Olaju ati iṣe ode toni lo mu ki ọpọ ma mọ ipa pataki ti Iyalọja n ko lawujọ.

Ohun ti o mu gbogbo atotonu yi wa ko ju awuyewuye to nlọ lọwọ lori jijẹ oye iyalọja ati babalọja nilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo lasiko yii.

Eyi lo mu ki Honorebu Adeniyi Adebisi to jẹ kọmiṣọna fun ọrọ okowo nipinlẹ Oyo ni o to gẹẹ lorukọ Gomina Seyi Makinde.

Adebisi ni ijọba ti ṣetan lati wa ojutuu si ija ojoojumọ lori ọrọ iaylọja ati babalọja ni Ibadan lasiko yii ati pe ẹnikẹni ko gbọdọ pe ara rẹ bẹẹ titi ijọba Seyi Makinde a fi gbe igbesẹ to yẹ.

Ṣaaju naa ni ọrọ fifi iyalọja jẹ ni ọja ti wọn ti n ta nnkan elo kọmputa nipinlẹ Eko, Computer Village naa tri fa awuyewuye tẹlẹ.

Awọn onisowo kan n fapajanu lori bi wọn ti ṣe fẹ fi oye iyalaje ati babalaje lọlẹ ni ọja naa.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, ọja Komputa ati ohun to jọ mọ imọ ẹrọ kii ṣe ibi ti wọn ti n yan iyalọja.

Nibo la ti le yan Iyalọja?

Ọjọgbọn Bisoye Eleṣin to jẹ olukọ ede ati aṣa Yoruba ni fasiti ijọba apapọ nilu Eko salaye pe oye iyalọja kii ṣe eleyi ti eeyan a maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu nitori ipa ti wọn n ko.

O ni ni ilẹ Yoruba, Ọba lo maa n yan iyalọja ati iyalaje ati pe ko si oye to n jẹ Babalọja nitori awọn obinrin ni Yoruba gba pe wọn ṣe akoso ọja.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Onisowo kan lọja Komputa Village nilu Eko

''Ki a to le yan iyalọja, a gbọdọ beere pe igba wo lo ti de ibẹ, ipa wo lo ko ninu itẹsiwaju ọja ati pe iru ọja wo lo n ta nibẹ''

Ọjọgbọn Bisoye ni pẹlu bi ohun ti ṣe wo oye nipa ọja Komputa Village nilu Eko, iruwa ogiri wa ni o wa nibẹ, ko si jọ bi igba wi pe awọn obinrin maa n kopa ninu karakata nibẹ ni eyi ti ko ri bẹẹ ni ti ọja ilu Ibadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLateef Adedimeji: Owó wa kò bá máa jóná ṣùgbọ́n aàyè ọpẹ́ ń yọ fún wa

Dandan ni ki yiyan iyalọja ni kọnunkọhọ nibẹ

Aarẹ ẹgbẹ to n ṣe akoso ọja Komputa Village CAPDAN, Ọgbẹni Ahmed Ojikutu sọ fun BBC pe awọn lodi si yiyan Iyalọja nitori pe kii ṣe iṣẹ ata tita lawọn n ṣe nibẹ.

O ni bi wọn ba file ri Iyalọja fi lọlẹ ni Komputa Village l'Eko,iru rẹ yoo waye ni Abuja ati awọn ibo miran.

O ni lọwọlọwọ ẹka to n risi gbigbẹ ogun ti iṣẹ n samojuto awọn ati pe ifasẹyin ni yiyan Iyalọja yoo jẹ.

Ninu esi ti rẹ, Iyalọja kaafata ni gbogbo Eko,Folashade Tinubu Ojo ni ẹya kan lo n fi ẹhonu han.

''Ki lo de ti ẹya yi yoo dide pe awọn ko fẹ Iyalọja.Ṣe wọn ko ni awọn olori ọja nibi ti wọn ti wa ni?

Amọ ṣa Ojikutu fesi pada pe kii se ẹya kan ni o n fi ẹhonu han bi kii ṣe gbogbo awọn ti ọrọ kan ni ọja naa.

Ki ni ọna abayọ?

Pẹlẹ kutu lọrọ yi gba ni ohun ti ọjọgbọn Bisoye sọ nipa wiwa ọna abayọ si awuyewuye yi ọrọ iayalọja ati babalọja ni Ibadan ati ni ipinlẹ Eko.

''Komputa Village kii ṣe ọja aarọ, ọja iruwa ogiri wa ni, ti a ba wọ ọpọlọpọ awọn to n ta ọja nibi kii ṣe ẹya Yoruba nikan fun idi eyi, yiyan iyalọja le fẹ mu kọnunkọhọ wa''

Ọpọ lo ti n sọrọ lori igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati bẹrẹ iwadii to yẹ lori awọn to n ja si ipo yii ni Ibadan ati igbesẹ to yẹ ka gbe ṣaaju yiyan ni si ipo agba naa.

Image copyright @iyalojageneral
Àkọlé àwòrán Aworan Iyalaje kafata nilu Eko nibi ajọdun kan ni Ile Ifẹ

Elesin tẹsiwaju pe Oba nikan lo lagbara lati yan Iyalọja tabi ko si jẹ wi pe awọn obinrin ọja naa yan ẹnikan lara wọn ti wọn yoo si fi orukọ rẹ ranṣẹ si ọba tabi ẹka ijọba ti o n mojuto ọrọ yi.

Nnkan to yẹ ki wọn beere ni pe ta lo yan Iyalọja naa.

''To ba jẹ ijọba lo yan Iyalọja, ko si nnkan ti ẹnikankan le ṣe nitori pe ijọba lalaṣẹ lori oun gbogbo''

Ijọba ipinlẹ Oyo ti pe fun alaafia ni asiko yii laarin awọn ọja Ibadan.

Honorebu Adebisi ni iṣọkan lo n mu ọja dagba sii ni eyi ti yoo tubọ jẹki onikaluku maa ri taje ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTi o bá dá ara ẹ lójú, ki ẹni tó n ṣe irun kí n gbọ́?

Related Topics