South Africa elections: Ǹjẹ́ àlàfo tó wà láàrin àwọn olówó àti tálákà n fẹ̀ si ni?

Ọkunrin kan to n rin kọja ni ẹ̀gbẹ́ iwe ipolongo ibo ẹgbẹ́ oṣelu ANC ni Johannesburg

Ọjọ kẹjọ, oṣu Karun un ni eto idibo yoo waye l'orilẹede South Africa, ti alafo to wa laarin awọn olowo ati otoṣi si jẹ ọ̀rọ̀ gboogi.

Oun lo ni idagbasoke awọn ileeṣẹ julọ ni Afrika - ṣugbọn otun jẹ ọ̀kan lara awọn orilẹede ti aidọgba pọ si ju ni agbaye.

Ẹgbẹ́ alatako sọ pe eyi ti buru si i l'abẹ iṣejọba ANC to ti wa ni iṣakoso fun bi aadọta ọdun.

Ṣugbọn ṣe lootọ ni?

Ṣiṣe odiwọn aidọgba

Oṣuwọn kan ti awọn onimọ nipa ọrọ aje maa n lo lati mọ bi aidọgba ṣe pọ to ni orilẹede kan ni a mọ si oṣuwọn Gini. O da lori iye owo ti kaluku n gba fun iṣẹ́ to ba ṣe - bi owo naa ba ṣe pọ si, ni aidgba naa yoo ṣe pọ to.

Ko sọ gbogbo otit ibẹ, ṣugbọn o jẹ ibi ti a ti le bẹrẹ si ni ṣagbeyẹwo aidọgba ni South Africa. ati afiwe rẹ̀ pẹlu awn orilede to ku.

South Africa is more unequal than others

Gini score

Figures for 2014 except Namibia (2015) and US (2013)
Source: World Bank data

Nipasẹ oṣuwọn yii, ati lilo akọsilẹ ti Banki Agbaye fi sita, South Africa lo ni ipele aidọgba ju ni agbaye.

Awọn orilẹede to mu ile ti i, Namibia ati Mozambique si n tọ ọ lẹyin gbagbaagba, ti Brazil naa si ti fẹ ẹ wa ni awujọ awọn mẹẹrin to wa l'oke.

Ti a ba wo ayipada to ti ba oṣuwọn yii, ti a si ṣagbeyẹwo rẹ lati asiko ti ẹgbẹ ANC ti gba ijọba l'ọdun 1994, aidọgba ga si laarin ọdun 1990 si 2005.

Ko si si ayipada gboogi kankan lati igba naa.

High inequality has not changed

Gini score

Source: World Bank data

Nitori naa, ti a ba lo akọsilẹ Gini, awọn to n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iṣejọba ẹgbẹ ANC ko parọ́ pe aidọgba pọ ni South Africa

Ṣugbọn irọ ni wọn pa pe o n buru u si, paapa lati bi ọdun mẹwaa sẹyin ti akọsilẹ wa fun.

Idagbasoke ọrọ̀ ajé ti ko tete dagba

Fun ọpọlọpọ dun lẹyin to de iṣakoso, ijọba ANC gbiyanju ninu mimu adinku ba ìṣẹ́, o si mu ayipada ba awọn nkan amayedrun to ṣe koko.

Eyi ṣeeṣe nitori pe ọ̀rọ̀ aje dagba soke daada - ṣugbọn ni bayii, ifasẹyin ti de ba a.

Esi rẹ̀ ni pe, awọn ọmọ orilẹede South Africa kúṣẹ̀ẹ́ lasiko yii.

Iye owo ti ẹni kọọkan n pa wọle ti dikun lati ọdun 2010.

Joblessness rises as growth slows

Source: World Bank

Aisi iṣẹ́ n pọ si lojoojumọ lasiko yii.

Olori ẹgbẹ alatako, Democratic Alliance, Mmusi Maimane sọ pe ko ti i si aridaju pe alafo to wa laarin awọn olowo ati talaka yoo di pa.

Ọ̀kan lara awọn minisita to wa ni iṣakoso aarẹ South Africa, Nkosazana Dlamini -Zuma sọ pe ''aidọgba kọ̀ lati dinku.''

Njẹ ìṣẹ́ ti buru jai si?

Pẹlu oṣuwọn ijọba South Africa fun ìṣẹ́ - ile ti owo to n wọle fun wọn ba kere si Dọla marunlelaadọta l'óṣù - akọsilẹ ijọba fihan pe afiwe yii ti dinku lati ìdá mọkanlelaadọta si mẹrindinlogoji laarin ọdun 2006 si 2011.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọdun 2015, afiwe naa ti lọ soke si ìdá ogoji.

Ọmọ orilẹede South Africa kan to jẹ onimọ nipa ọ̀rọ̀ aje, Carlene van Westhuizen, sọ ninu abọ iwadi kan to ṣe fun ile ẹ̀kọ́ Brookings Institution to wa ni orilẹede America sọ pe "awọn talaka ko fi bẹ ẹ janfaani idagbasoke to ba ọrọ̀ aje."

Image copyright AFP

Abọ iwadi kan ti Banki Agbaye ati ijọba South Africa jọ ṣe fihan pe awọn iyatọ to wa ninu owo ti onikaluku n gba lẹnu iṣẹ́ wọn jẹ ọ̀kan pataki lara ohun to fa aidọgba ni South Africa laarin ọdun 2006 si 2015.

''Nini anfaani si ipele eto ẹ̀kọ́ to ga ati owo oṣu ti ko dawọ duro jẹ pataki lara awọn nkan ti yoo mu ko ṣeeṣe fun awọn ẹbí lati le ni eto ọrọ̀ aje to f'ẹsẹ mulẹ ni South Africa."

Wọn gboriyin fun eto riran araalu lọwọ, pe o n mu adinku ba ìṣẹ́, ṣugbọn titẹsiwaju ninu rẹ yoo ni ipa to l'agbara ninu eto inawo ijọba.

Awọn wo ni ọ̀rọ̀ yii kan ju?

Ọpọ ninu awọn ọmọ South Africa to jẹ alawọ dudu ti n gbe ninu ìṣẹ́ lati atọdun-mọdun, ta a ba ni kafiwe awọn to jẹ Asia ati awọn ọmọ South Africa to jẹ alawọ funfun.

Laarin ọdun 2011 si 2015, iyatọ to wa laarin awọn alawọ dudu ati funfun to n gbe ninu ìṣẹ́ pọ si, gẹgẹ bi akọsilẹ ijọba ṣe sọ.

Poverty and race in South Africa

Percentage living below poverty line

Source: Statistics South Africa

Ìdá mẹwaa ati diẹ ni awọn alawọ funfun to n ṣiṣẹ - ṣugbọn wọn n gba to ilọpo mẹta owo ti awọn ọmọ South Africa to jẹ alawọ dudu, to ko ìdá mẹta ninu mẹẹrin laarin awọn oṣiṣẹ.

Banki Agbaye sọ pe, botilẹjẹ wi pe owo iṣẹ́ ti lọ soke fun gbogbo ẹya, owo ti awọn ti owo oṣu wọn pọ pupọ n lọ soke si ni bi i ilpo meji ju ti awọn ti owo iṣẹ́ wọn kere lọ