John Onaiyekan: Ìtìjú ni fún mi láti rí àwọn ọmọbìnrin Nàìjíríà tó ń ṣe aṣẹ́wó ní Italy

Ẹniọwọ John Onaiyekan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn to n fi orilẹede Naijiria silẹ ni wọn wa lati agbegbe gusu ipinlẹ Edo

Biṣọbu agba ijọ aguda nilu Abuja, ti ṣekilọ fun awọn adari orilẹede Naijiria pe awọn gan ni wọn n sọ orilẹede Naijiria di koṣeegbe fun ọpọlọpọ awọn ọdọ eyi to si n mu wọn maa tẹ ọkọ leti roke okun.

Ẹniọwọ John Onaiyekan ṣalaye pe bi o ba jẹ pe oun ni aarẹ orilẹede Naijiria lọwọlọwọ bi nnkan ṣe ri yii, nṣe ni oun yoo kọwe fi ipo silẹ lẹyẹ o sọka.

O bu ẹnu atẹ lu awọn olori orilẹede Naijiria pe ti ara wọn nikan ni wọn n le kiri nipa kikọ ile nlanla, ti wọn si n rinrinajo kaakiri orilẹede Naijiria.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa ṣalaye pe oju n gba oun ti fun bi awọn ọmọbinrin orilẹede Naijiria ti wọn ko lọ ṣe owo kotọ loke okun ṣe di alagbe lawọn opopona ilu Rome atawọn ilu miiran lorilẹede Italy.

Ẹniọwọ Ọnaiyekan ba awọn oniroyin sọrọ ṣaaju ipejọpọ ijọ Katoliiki lati sọrọ lori bi awọn eeyan ṣe n lọ kuro lorilẹede Naijiria eleyii ti wọn fẹ ṣe ni ọjọ iṣẹgun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Biṣọ̀bu ijọ Katoliiki niluu Abuja, Ẹniọwọ John Onaiyekan kilọ pe awọn adari lorilẹede NAijiria gbọdọ ṣe ohun to tọ fun atunṣe ati idagbasoke orilẹede Naijiria

Ni oṣu keji ọdun yii ni aarẹ Buhari bori ninu idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria to jẹ orilẹede to n pọn epo rọbi julọ nilẹ Afirika ṣugbọn ti ida kan ninu mẹrin awọn eeyan rẹ ko ri iṣẹ ṣe.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn ti gbiyanju ati rin irinajo to lewu ninu gidigidi gba aṣalẹ ilẹ Sahara Desert ati ori okun Meditaranean lati lee de ilẹ Yuroopu.

Iye awọn to n lepa irinajo yii ti n dinku lati ẹbẹrun lọna ogoji to gba ori okun gunlẹ si orilẹede Italy lọdun 2016 si ẹgbẹrun kan o le igba ati aadọta ni ọdun to kọja, eleyii ti ko yẹ lori igbesẹ mawoju ẹ eleyi ti ajọ orilẹede Yuroopu gbe lati kọ oju oro sawọn to n ṣowo fifi eeyan ṣọwọ soke okun lọna ti ko bofinmu.

Ọpọ awọn to n fi orilẹede Naijiria silẹ ni wọn wa lati agbegbe gusu ipinlẹ Edo.

Awọn obinrin ati ọdọbinrin ni wọn saba maa n ṣubu sinu ikẹkun yii ni ilepa iṣẹ, ṣugbọn lẹyin o rẹyin wọn yoo di aṣẹwo.

Àkọlé àwòrán Onaiyekan rọ ijọba lati 'tun Naijiria ṣe'

" Ma jẹ ki n pe aja lọbọ, oju n gba mi ti, oju n timi- emi iranṣẹ Ọẹọrun lati ilu nla bii Abuja, mo n lọ ni oju popo ni ilu Rome, Milan, Naples, ki n si maa ri awọn ọmọ mi ni oju popo fun tita," Ẹniọwọ naa fi to BBC leti lẹyin ipade oniroyin wọn naa.

"Oju n ti mi, maa duro lati ki awọn miran ninu wọn gan-ko tilẹ rọrun lati ba wọn jiroro nitori pupọ ninu wọn lo jẹ pe ati abule ni wọn ti wa lai ni imọ ẹkọ kankan. Imọ ti wọn ni ko ju eyi ti wọn yoo fi ṣe owo nọbi wọn loju popo orilẹede Italy.-oju n ti mi gidigidi."

O ni aini afojusun ati iran to kuna awọn oloṣelu Naijiria n ṣakoba fun orilẹede yii, bẹẹ lo rọ wọn pe bi wọn ko ba ni afojusun lori bi wọn yoo ṣe gbe orilẹede Naijiria goke agba, ki wọn yago fun ipo oṣelu.

O wa rọ ijọba lati 'tun Naijiria ṣe' ki awọn ọdọ lee dẹkun sisa kuro lorilẹede Naijiria lọ soke okun.