Obafemi Awolowo University: Àwọn tó jí olùkọ́ wa gbé kò tíì sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbà

Image copyright oau
Àkọlé àwòrán Ní ọjọ Aiku ni wọn ji Ọjọgbọn Adegbẹhingbe gbe.

Awọn ajinigbe ti ji olukọ agba fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa nilu ile Ifẹ kan, Ọjọgbọn Yinka Adegbehingbe gbe.

Agbegbe ikire si apomu ni opopona marosẹ Ifẹ si Ibadan ni wọn ti ji ojọgbọn naa gbe.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC news Yoruba, alukoro ileewe fasiti OAU, Abiọdun Olarewaju ṣalaye pe ni nnkan bi agogo mẹjọ abọ si mẹsan alẹ ọjọ aiku ni wọn ji ọjọgbọn naa gbe.

"Ileewe ẹkọ imọ ilera ati iṣegun ni ọgba fasiti naa ni ọjọgbọn Adegbẹhingbe ti n ṣiṣẹ. Ohun ati iyawo rẹ ni wọn jijọ n rinrin ajo lasiko ti awọn ajinigbe naa ṣọṣẹ."

O ni titi di asiko ti oun fi n ba BBC sọrọ, awọn ajinigbe naa ko tii kan si ẹbi tabi ileewe naa lori ohun ti wọn fẹ ki wọn to lee da Ọjọgbọn naa pada.