Bukola Saraki: Ìwà àrékérekè ni ilé mi tí EFCC tì pa

BUKOLA SARAKI-EFCC Image copyright WIKIPEDIA
Àkọlé àwòrán Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, efcc ti ile saraki to wa ni 15a, 15b ati 17 to wa ni agbeegbe MacDonald Road, Ikoyi, Lagos.

Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki ti ni ìwà arekereke ati jibiti ni ile oun ti wọn ti pa ni Ikoyi ni ilu Eko.

Iroyin naa tan kalẹ pe ajọ to n gbe ogun ti iwa jẹgudujẹra, EFCC ti ile Saraki to wa ni 15a, 15b ati 17 to wa ni agbeegbe MacDonald Road, Ikoyi, Lagos.

Bi o tilẹ jẹ pe nigba ti ile iṣẹ BBC kan si ajọ EFCC, wọn ni "A ò tì ilé Saraki pa ní'lú Eko - EFCC". Bẹẹ sini ṣaaju wọn ti ni Bukola Saraki kò kọjá òfin - EFCC.

Saraki ninu atẹjade to fi lede gba ọwọ agbẹnusọ rẹ, Yusuph Olaniyonu, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC lori awọn ile rẹ ti wọn gbẹsẹ le.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

Saraki ni awọn ile wọnyii kii ṣe ohun ti a n fi bo, ati wi pe awọn ile ti oun sọ fun ijọba pe o wa ni ikawọ oun ni awọn ile wọnyii lasiko ti oun wa ni isejọba.

Bi o tilẹ jẹ pe Ajọ EFCC ti sọ wi pe awọn ko gbegi le ile rẹ to wa ni Ikoyi, Saraki ni EFCC tun rawọ le ẹsun ti ile ejo fi da oun lare ni.

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ lè nífẹ sí