Whatsapp: Àwọn gbéwiri s'àtakò sí Whatsapp, yára ‘Update’ rẹ̀

Whatsapp Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ile isẹ ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ Whatsapp ti ni ki awọn 1.5bn eniyan to n lo ki wọn 'update Whatsapp' wọn.

Awọn onijibiti ‘hackers’ ti fi imọ ẹrọ ‘spy software’ sori ẹrọ ilewọ awọn eniyan, eleyii ti wọn fi lee wo gbogbo ohun to wa lori ẹrọ ilewọ naa.

Nitori naa, alamojuto whatsapp ti ni ki gbogbo ẹni to n lo whatssap lọ ṣe eto ayipada ti wọn pese pẹlu 'update'.

Whatsapp to jẹ wi pe Facebook lo ni i, sọ wi pe awọn aṣebajẹ yii n lepa awọn eniyan kan ni wọn se se eyi, ati wi pe awọn gboogi ni ẹka imọ ẹrọ lo se isẹ naa.

Amọ, Facebook ni awọn ti wa wọrọkọ fi sada, ati wi pe ọna abayọ ti de si isoro naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

Facebook ni ‘Israeli security firm NSO Group’, lo se isẹ ibi yii. ọna ti wọn gba ni pe, wọn yoo pe ẹrọ ilewọ rẹ lori Whatsapp, boo gbe e, boo gbe e, ‘spy software’ yoo wo ori ẹrọ ilewọ rẹ, eleyii ti yoo fun wọn ni anfaani lati wo gbogbo ohun to ba wa lori ẹrọ ilewọ rẹ.

Ti wọn si parọwa si eniyan to le ni biliọnu kan to n lo ‘Whatsapp’ lati lọ tẹ ‘Update’ ẹrọ ikansiẹni yii ki awọn asebi ma baa ri gbogbo ohun ti wọn n ko pamọ si ori ẹrọ ilewọ wọn.