Pool drown: Ìbejì ọmọ ọdún méjì Mínísítà fún ọ̀rọ̀ omi bá odò lọ

Aworan iya to padanu awọn ọmọ rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aworan yi la fi ṣe akawe iya to padanu awọn ọmọ rẹ

Ina ọmọ ti jo Minisita fun ọrọ alumọni omi lorileede Uganda, Ronald Kibuule, pẹlu bi awọn ọmọ ibeji ọkunrin rẹ ṣe bodo lọ.

Awọn ọmọ naa ti wọn jẹ ọmọ ọdun meji ni a gbọ pe wọn ku si inu omi adagun ti wọn ṣe lọjọ si inu ile wọn to wa ni ilu Mbala.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vision Newspaper ṣe jabọ, Roman Kato ati Raiding Wasswa n ṣere ninu ọgba ile wọn ni lasiko ti iṣẹlẹ aburu yii waye.

Awọn ọmọ ọdọ meji ti wọn n tọju awọn ọmọ naa lawọn agbofinro ti mu lati wadi ọrọ lẹnu wọn.

Alukoro ọlọpaa nilu Kampala, Patrick Onyango sọ fun awọn akọroyin pe baba ati iya awọn ọmọ naa ko si nile nigba ti iṣẹlẹ yi ṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi tipá bá ọmọ méjì lòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjàmbá Ibadan: Abiyamọ tó pọn ọmọ sẹ́yìn kú tọmọ-tọmọ

Wọn ni o ṣeeṣe ki o jẹ pe ọkan ninu awọn ibeji naa lo kọkọ jabọ sinu omi ti ikeji rẹ naa si ja sodo nigba ti o n gbiyanju lati doola rẹ.

Awọn eeyan ti n ba mọlẹbi Minisita naa kẹdun iku awọn ọmọ rẹ loju opo Twitter

Related Topics