US Embassy ní bí o bá fẹ gbà Visa, àfi kò yọjú funrararẹ

US Embassy Abuja Image copyright Twitter/@USEmbassyAbuja
Àkọlé àwòrán US Embassy Abuja

Ileeṣẹ aṣoju Amerika lorileede Naijiria ti mu iyipada ba eto irina lati Naijiria lọ si ilẹ wọn.

Bẹrẹ lati oni lọ,bo lọ amerika tẹlẹ, boo lọ ri,afi ko yọju sileeṣẹ wọn ki wọn to le fun ọ ni iwe irina oke okun

Wọn fi ikede yi soju opo wọn kan lori ayelujara ti awọn eeyan kan si ni awọn ri ikede yi loni ti awọn fẹ kowe gba iwe irina naa loni.

Image copyright US Embassy in Nigeria

Ilana to wa nilẹ tẹlẹ fayegba ki awọn eeyan to ba fẹ tun iwe irina( B1/B2 fun awọn arinrinajo igbafẹ) gba fi iwe wọn ranṣẹ sinu apo iwe si ileeṣẹ to n ṣoju Amerika ni Naijiria.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe wọn ko ni yọju lati ṣe ifọrọwanilnuwo kankan titi ti wọn yoo fi gba iwe irina tuntun mi.

Abiyamọ ò! Ìbejì ọmọ ọdún méjì Mínísítà fún ọ̀rọ̀ omi bá odò lọ

Leah Sharibu pé ọmọ ọdún 16 ní àhámọ́ Boko Haram

Àgbedọ̀! 'Ò ń f'ẹ̀mí ara rẹ wéwu tó bá fẹ́ kọ́kọ́ yẹ ọlọ́pàá wò'

Akeredolu, Ọgá NDLEA lọ kọ nípa gbíngbin igbó ní Thailand

Aṣẹ yi ko kan awọn ti wọn ba f gba iwe irina awọn aṣoju(Diplomatic Visa,A,G ati Nato).

Loṣu Kẹfa ọdun 2014 ni ọfisi Amerika ni Naijiria kede pe awọn ti bẹrẹ eto ilana fifi iwe irina ranṣẹ ninu apo iwe fawọn ti iwe irina wọn ko ba ti jọba fun igba to ju ọdun meji lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'