Kano Sharia Police: Ènìyàn Kano ọgọ́rin lo ti wà látìmọ́lé nítorí wọn jẹun nínú ààwẹ̀.

Abo oun ti won n pin Image copyright MOhammed El-Shaeed
Àkọlé àwòrán Ènìyàn tó lé ní ọgọ́rin ní ọlapàá Shaira Kano mu nítori Ounjẹ

Ọlọpàá Sharia ní ìpínlẹ̀ Kano ti mú ènìyàn tó tó ọgọ́rin nítori pe wọn ń jẹun ní àsìkò ààwẹ látigba ti oṣù Ramadan ti bẹ̀rẹ̀.

Agbẹnusọ ọlópàa Hisbah Adamu Yahaya sọ fún ilé iṣẹ́ BBC pe àwọn ti àwọn gbámu ni àwọn mùsùlùmí ti wọn o gbà ààwẹ̀ lásiko Ramadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRAMADAN: Onímọ̀ ẹ̀sin sọ nípa isẹ́ láádá àti làádà

Adamu ni iye àwọn ènìyàn ti àwọn ti mú ni àsìkò yiìí ti lọ silẹ̀ ju ti atẹyin wa lọ, èyí túmọ si pé ìgbìyànjú àwọn ti n ni ipa rere

Ọ̀pọ̀ àwọon ti a gbámu pe wọn ń jẹun, ìgbà àkọkọ rèé ti a o mú wọn fún ẹsun ounjẹ jijẹ, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ wa ṣe ri àwọn ènìyàn yìí, ẹ̀tọ́ wa ni láti gbàwọn nimọran sùgbọ̀n ti a ba mú wọn ní èèkeji o di ẹ̀wọn tààrà ni

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'

Agbẹnusọ náà ní ti ẹnikẹni ba mọ ibi ti musulumi kankan ba ti n jẹun nile ounje ki wọn jẹ ki awọn gbọ ki àwọn ba le gbe ìgbésẹ̀.

Ǹkan ti a mọ ni pe àwọn ènìyàn máa n sápamọ lọ jeun, "sùgbọn ti ẹ ba mọ ile ounjẹ tabi ile itura ti àwọn ènìyàn ti ń jẹun, ẹ jẹ ki a mọ láti gbe igbesẹ̀ to yẹ".

Àkọlé àwòrán Kano Sharia Police: Ènìyàn Kano ọgọ́rin lo ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí wọn jẹun nínú.

Adamu sọ pe àwọn musulumi nikan ni àwọn n mu, ati pe àwọn ẹlẹsin miiran ni ẹtọ láti jẹun bo se wu wọn. O fi kún un pe ti àwọn ba ṣeesì mú ẹni ti ó jẹ onígbagbọ ti ó ba ti le ṣàlàye ara rẹ àwọn yóò fi ẹni náa silẹ ni kiakia.

Òní ní ààwẹ Ramadan pe ọjọ mẹ́wàá sùgbọ́n ààwẹ ku ọjọ mọ́kandinlogun si ogunjọ ti ààwẹ náà yóò pari ti ọdun itunu ààwẹ yóò si waye.