Ekiti Sack: Kí ló dé tí àwọn ìjọba ń yọ òṣìṣẹ́ bíi ẹní yọ jìgá ní gbogbo ìgbà?

Aworan Gomina Kayode Fayemi ati Ayodele Fayose Image copyright Facebook/KayodeFayemi/Ayodele Fayose
Àkọlé àwòrán Ijọba awọn Gomina mejeeji yi dabi ẹni pe wọn taka ẹni to le yọ oṣiṣẹ laarin wọn

Bi erin meji ba n figagbagba, dajudaju koriko ibẹ ni yoo fori ko.

Rẹgi ni ọrọ yii ni ipinlẹ Ekiti nibi ti ijọ́ba to wa lori oye kede pe awọn yoo da awọn kan ti ijọba ana yọ lẹnu iṣẹ pada ti awọn yoo si mu atunṣe ba eto igbanisiṣẹ ti ijọba ana ṣe.

Ni ṣoki ohun ti ''atunṣe'' tumọ si ni pe awọn yoo wọgile eto igbanisiṣẹ ti ijọba Fayose ṣe ati pe awọn to gba siṣẹ ni igba perete si ipari saa ijọba rẹ yoo padanu iṣẹ wọn.

Ninu atẹjade kan ti Kọmisana feto Iroyin, irinajo igbafẹ ati ilanilọyẹ Muyiwa Olumilua fi sita, o ni a igbaniṣisẹ to waye lẹyin idibo Gomina losu Keje ọdun 2018 ko tẹle ilana to yẹ.

''Fun idi eyi, a ti wọgile ti ko si fẹsẹ rinlẹ''

"Eeyan to gbajẹ lẹnu eeyan,apaayan ni"

Ọmọ ipinlẹ Ekiti kan to jẹ oṣiṣẹ ijọba to ba BBC sọrọ to ni ki a fi orukọ bo ohun lasiri ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba Kayode Fayemi yii.

O ni lootọ ni pe ohun ti ijọba Fayose naa ṣe nigba ti o de ori alefa ni pe o yọ awọn ti Fayemi gba siṣẹ ṣugbọn ki wọn jijọ ma taka ẹni to le yọ oṣiṣẹ ko dara to.

Image copyright EKITI STATE GOVERNMENT

Ọjọ iwaju awa ọdọ ni wọn fi n ṣere yẹn. Kini ki ni to ti n bọ iyawo ati ọmọ pẹlu iru iṣẹ bẹ wa ṣe nigba ti wọn ba le lnu iṣẹ?

Ati ẹni gba iṣẹ ati ẹni to padanu iṣẹ, Ekiti lawọn mejeeji yoo pa owo pada wa.Iru nnkan bayi ko suwọn fara ilu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Gomina tẹlẹ ri Lere Olayinka ti fi ọrọ ti rẹ naa sita loju opo Facebook pe Fayose iwa ika gba ni bi ijọba Fayemi ti ṣe yọ eeyan ẹgbẹrun meji ti ijọba Fayose gba siṣẹ.

Olayinka ni Fayemi ti kọ orukọ rẹ sinu iwe itan gẹgẹ bi ẹni to n mu inira ba awọn eeyan ipinlẹ naa

Ohun ti o tọ ni Fayemi ṣe,igbaniṣiṣẹ makaruru ni Fayose ṣe

Arakunrin miiran to ba ikọ BBC sọrọ ti ohun naa ni ki wọn ma darukọ tirẹ naa ni ''gbogbo nnkan lo leto amọ bi ijọba ba fi oṣelu wọ gbigbani siṣẹ ko le labọ ti yoo da''

O tẹsiwaju pe ijọba Fayose ko to ri awọn eeyan ṣeto igbanisiṣẹ ati pe awọn to fun ni iṣẹ naa ko fi taratara ni igbagbọ si iṣẹ naa.

''Bi ẹ ba kaakiri ilu, ẹ ko ni gbọ ariwo lori bi wọn ti ṣe yọ wọn niṣẹ nitori awọn naa mọ pe ojoro ni iṣẹ ti wọn fun wọn.''

Ọna Abayọ

Awọn mejeeji ti o ba BBC Yoruba ni o di dandan ki ijọba ma tẹle ilana to yẹ nigbakigba to ba fẹ gbani siṣẹ.

Wọn ni ko bojumu ki ara ilu ma padanu iṣẹ lasiko yii ti ati ri iṣẹ jẹ ipenija nla.