Kogi, Bayelsa Governorship Elections: INEC kéde ọjọ́ tuntun

Ami idanimọ ajọ INEC Image copyright INEC

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti kede ọjọ tuntun fun eto idibo sipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Eto idibo naa to yẹ ko waye l'ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni yoo waye bayii lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, 2019.

INEC kede ọjọ tuntun naa lori opo ayelujara Twitter rẹ.

Kí ló dé tí ìjọba Èkìtì ń fí àwọn òṣìṣẹ́ ṣé ''helo-helo testing"?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Ajọ INEC sọ pe sisun ti wọn sun eto idibo naa siwaju ko ṣẹyin bi ijọba ipinlẹ Bayelsa, ati awọn ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ, to fi mọ awọn olori ẹsin, ṣe kọwe ẹbẹ si ajọ naa lati sun un siwaju nitori pe ọjọ ti wọn kọkọ da fun idibo jẹ ọjọ kan naa pẹlu eto idupẹ ọdọọdun ti wọn maa n ṣe ni ipinlẹ Bayelsa.