Operation Puff Adder: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé 93, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn 'AK47' àti aṣọ ṣọ́jà

Awọn aṣọ ọmọ ogun ati ibọn ti wọn gba lọwọ awọn afurasi naa Image copyright Nigeria Police
Àkọlé àwòrán Yatọ si awọn nkan ija oloro, awọn ọlọpaa tun ri awọn aṣọ ọmọ ogun tgba lọwọ awọn afurasi naa.

Ọwọ ileesẹ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹtalelaadọrun ni awọn agbegbe kan ni ẹkun Ariwa Naijiria.

Awọn afurasi naa ni ọwọ awọn ọmọ ikọ pataki ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ lati gbogun ti ijinigbe, Operation Puff Adder tẹ ni ẹkùn Ariwa Naijiria.

Lara awọn nkan ti awọn ọlọpaa ka mọ awọn afurasi naa lọwọ ni ibọn AK47 marundinogoji, ẹẹdẹgbẹta ọta ibọn, to fi mọ aṣọ ọmọ ogun mẹwaa, ọkọ ijagun meji ati awọn nkan ija oloro mi i.

Image copyright Nigeria Police
Àkọlé àwòrán Ọga Agba ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu n ṣe ayẹwo awọn nkan ija oloro ti ọwọ tẹ

Nibayii, awọn ọtẹlẹmuyẹ nileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati mọ orisun ti awọn afurasi naa ti n ri awọn nkan ija oloro ti wọn n lo. Ati lati mọ awọn to jẹ alatilẹyin wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muhammed Adamu dupẹ lọwọ awọn araalu fun bi wọn ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn iroyin to ran an lọwọ lẹnu iṣẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionZainab Aliyu: Mo sọkún títí, ojé tán lóju mi ni àhámọ Saudi

Bakan naa lo sọ pe kileeṣẹ ọlọpaa ko ni dawọ duro lati ri i daju pe aabo to peye wa ni awọn opopona nlanla ni Naijiria.