'Ìyá mi kú nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ta, bàbá mi sálọ, orí mi jí sí ìwé ṣùgbọ́n n kò rí ìrànwọ́'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Hungary lè di àlá làsàn fún Pẹlumi tí kò bá rì N1 mílíọ́nù láti kòpa nínú ìdíje Olympiad ní orílẹ̀èdè náà

Ṣe bi iṣu ma ta ninu ebe, ẹrin a pa ẹẹkẹ oloko ni. Iyi obi ni ki ọpọlọ ọmọ o ji pepe ki o si kogoja ninu ẹkọ rẹ. Idunnu nla ni fun iya-iya Pẹlumi Akinṣọla akẹkọ girama kan ni ilu Ibadan fun ọpọlọ pipe ti Eledua fi taa lọrẹ.

Lootọ Pẹlumi ko tii pe ọmọ ọdun mẹta nigba ti iya rẹ ti jade laye ninu ijamba ọkọ, bẹẹsi ni baba rẹ pẹlu ti sa fi ile silẹ, ṣugbọn iṣoro kan lo n bẹ loju ọna Pẹlumi bayii.

Ki ni iṣoro yii gan ati pe ki ni ohun to ṣokunfa iku Iya rẹ, bi baba rẹ ṣe sa kuro nile ati ọgbẹ ọkan to wa lọkan iya iya rẹ bayii?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: