Adeleke: Ajayi Shuaib tí wọ́n ní ó pe Adeleke lẹ́jọ́ ní irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdeleke fake certificate allegation: Ajayi Shuaib tí wọ́n ní ó pe Adeleke lẹ́jọ́ ní irọ́ n

A n jẹ ekuru ọrọ ko tan lawo, n ṣe lawọn kan tun n gbọn ọwọ rẹ sinu awo lọrọ awuyewuye lori ẹsun ayederu iwe ẹri ti o wa lọrun oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke bayii.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa ti kọkọ gbe e lọ si ile ẹjọ fun ẹsun yii ni ilu Abuja laipẹ yii, ẹjọ miran tun dide lori ẹsun yii kan naa ni ọjọ kẹtala oṣu karun ni ile ẹjọ giga apapọ to wa ni ilu Oṣogbo. Gẹgẹ bii iroyin ṣe sọ, Ọgbẹni Ajayi Shuaib to pe ara rẹ ni ẹni ọrọ n dun labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn pe o pe ẹjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn bayii, arakunrin to n jẹ Ajayi Shuaib ọhun lo tun ti wa si gbangba bayii pe wọn parọ mọ ohun ni, ohun kọ lo gbe ẹjọ tako Adeleke lori ẹsun ayederu iwe ẹri naa.

Ọgbẹni Ajayii ni eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Bukọla Adewale lo fi ọna eburu lo orukọ oun lati pe ẹjọ naa lẹyin to ti wa ba oun nile pe oun ti ba oun ri iṣẹ.

O ni Bukọla Adewọle yii lo fi ye oun pe 'oun ti ba mi ri iṣẹ ti mo nwa ati pe wọn yoo nilo iwe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mi, awọnran ilewọ Passport fun iṣẹ naa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN1 mílíọ́nù leè mú kí, orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Pẹ̀lúmi Akínṣọlá ó pàdánú àmì ẹ̀yẹ Olympiad

Ni ọjọ kẹwa oṣu karun ọdun 2019 ni Bukọla Adewale tun pe mi pe ki n pade oun nilu Oṣogbo ti mo si jẹ ẹ ni hoo. Ni ibẹ lo ti mu mi lọ ba awọn eeyan kan. Wọn ni ki n buwọ lu awọn iwe kan ti mo si buwọlu wọn, wọn si gba aworan ilewọ mi, mo si gba ile lọ."

Ajayi Shuaib ni oun ko mọ ohunkohun mọ lẹyin eyi .

Image copyright Ademola adeleke
Àkọlé àwòrán Arakunrin Shuaib ni oun ko pe ki ẹnikẹni o lo orukọ oun lati pe ẹjọ.

Amọṣa orukọ Ajayi Shuaib ni wọn ṣalaye pe o han ninu iwe ipẹjọ ti nọmba idanimọ rẹ jẹ FHC/OS/16/19 niwaju ile ẹjọ giga apapọ to wa nilu Oṣogbo pe o pe ẹjọ lorukọ ara rẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa kan lati fi ẹhonu han lori ẹsun ayederu iwe ẹri ti wọn fi kan Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Ninu iwe ibura to ṣe ni ile ẹjọ giga apapọ naa, o ni "iyalẹnu nla lo jẹ fun mi nitori n ko sọ fun ẹnikẹni pe mo nii lọkan lati gbe ẹnikẹni lọ si ile ẹjọ, ambọsibọsi, oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ti mo n fi gbogbo igba ṣe atilẹyin fun."

Arakunrin naa ni oun ko pe ki ẹnikẹni o lo orukọ oun lati pe ẹjọ.