Kidnapping: ASUU kọminú lórí ọwọ́jà ìjínigbé, pè fún àbò fáwọn olùkọ́ fásitì

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapping: ASUU kọminú lórí ọwọ́jà ìjínigbé, pè fún àbò fáwọn olùkọ́ fásitì

Awọn olukọ fasiti lorilẹede Naijiria ni pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii o ṣeeṣe ki awọn gunle iyanṣẹlodi lati fi ẹhonu han lori bi jiji awọn olukọ fasiti gbe ṣe wa di tọrọ fọnkale lorilẹede Naijiria.

Alaga, ẹgbẹ ASUU ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ọmọwe Adeọla Ẹgbẹdokun lo kede eyi nibi ipade awọn olukọ fasiti naa lori bi awọn ajinigbe ṣe ji ọkan ninu awọn olukọ fasiti naa gbe ni aipẹ yii.

Ṣọ́ra, 'Loom Money Nigeria' kọ́ ni ètò sogún-dogójì tí yóò kọ́kọ́ wọ Nàìjíríà

'Iṣẹ́ ni mó ń wá kí wọ́n tó lo orúkọ mi fi gbé Sẹ́nétọ̀ Adeleke lọ sí ilé ẹjọ́'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN1 mílíọ́nù leè mú kí, orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Pẹ̀lúmi Akínṣọlá ó pàdánú àmì ẹ̀yẹ Olympiad

Ọmọwe Ẹgbẹdokun woye pe ọwọja iṣẹlẹ ijinigbe atawọn iwa ipa miran to n waye lorilẹede Naijiria bayii fihan pe ijọba ti kuna lori eto ipese abo fawọn eeyan orilẹede Naijiria.

O ni eyi ti o bani ninu jẹ julọ naa ni bi iṣẹlẹ ijinigbe ati igbesunmọmi naa ti ṣe sun de ipinlẹ Ọṣun nibi ti ọpọ n fi ọkan si gẹgẹ bii ọkan lara awọn ipinlẹ ti alaafia sodo si julọ lorilẹede Naijiria.

O ni ninu ibẹru-bojo lawọn olukọ ati akẹkọ n gbe bayii ni ọgba fasiti naa lẹyin ti awọn ajinigbe ji ọjọgbọn naa gbe ni opopona Ibadan si ifẹ to jẹ ọkan lara awọn ọna pataki to wọ ileewe naa.

Ni ọjọ karun oṣu karun ọdun 2019 lawọn ajinigbe ji Ọjọgbọn Adeyinka Adegbẹhingbe gbe ti wọn ko si fi silẹ afi igba ti wọn gba miliọnu marun naira lọwọ awọn eeyan rẹ.