Facebook: Naijiria wà lára àwọn orílẹ̀èdè tó ní ojú òpó ayédèrú

Facebook Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ile isẹ Facebook sọ ni oju opo rẹ pe awọn ti yọ oju opo ayederu 265 kuro ni ori ẹrọ ikansiraẹni rẹ.

Ile isẹ ikansiraẹni Facebook ti ni ogunlọgo oju opo to jẹ ayederu ni awọn ti wọgile nitori wọn fẹ lepa ilẹ Afirika.

Facebook ni ile isẹ kan ni orilẹede Isreal lo n pin awọn iroyin ẹlẹjẹ to nii se pẹlu eto oselu ati eto idibo ni awọn orilẹede si awọn oju opo ayederu yii lati da rogbodiyan silẹ.

Ọpọlọpọ awọn eniyan ni o bu ẹnu ate lu oju opo Facebook gẹgẹ bi oju opo ti o ni ayederu iroyin to gajulọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN1 mílíọ́nù leè mú kí, orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Pẹ̀lúmi Akínṣọlá ó pàdánú àmì ẹ̀yẹ Olympiad

Ile isẹ Facebook so ni oju opo rẹ pe awọn ti yọ oju opo ayederu ti ko din ni aadọrinlenigbadinmarun un ti orisun rẹ wa lati orilẹede Isreal lọ si awọn orilẹede ni Afrika kuro ori ẹrọ ikansiraẹni rẹ.

Awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni Nigeria, Senegal, Togo, Angola, Niger ati Tunisia pẹlu awọn agbeegbe kọọkan lati Latin America ati South East Asia.

Ti a ko ba gbagbe, ọdun 2016 ni Facebook ti bẹrẹ iwadii lori awọn iroyin ẹlẹjẹ to jade lasiko idibo sipo aarẹ ni ilẹ Amẹrika to waye ni ọdun naa, ti o si gbe aarẹ Donald Trump.