Saheed Oṣupa on Nigeria's Politics: Mi ò ní ìyàwó nílé, àmọ́ bí mo ṣe ní ọmọrẹpẹtẹ rèé

Saheed

Gbajugbaja olorin fuji lorilẹede Naijiria, Saheed Osupa ti sọ fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ wi pe oun ko ni iyawo ni ile, amọ oun ni ọpọlọpọ ọmọ to jẹ ti ti oun.

Saheed Osupa fi eyi lede lasiko to n ba BBC Yoruba fọrọjomitoro ọrọ lori oju opo ikansiraẹni Facebook ti BBC News Yoruba.

Osupa ni o ni idi ti oun ko fi ni iyawo si ile, amọ o parọwa si awọn ololufẹ rẹ lati fọkan balẹ.

Bakan naa ni olorin gbajugbaja naa sọ wi pe ọlọ́pọlọ pípé kò leè ṣe òṣèlú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, nitori iwa ẹgbin bii jẹgudujẹra ti o wọpọ ninu oselu orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

Saheed Osupa ni oun ko ni lọkan lati se oselu bayii nitori oun jẹ olooto eniyan ti awọn eniyan fọkan tan.

Àkọlé fídíò,

Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀