Rochas Okorochas ní ìlàkàkà àti gbé ìpínlẹ̀ Imo sókè ti sọ mí di ọlọ́dẹ orí

Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo n ṣi akanṣe iṣẹ kan lẹgbẹ rẹ ni gomina wike ati Rochas Okorocha duro si Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ awuyewuye lo n wọ tọ gomina Rochas lẹyin bayii ni ipinlẹ rẹ ati laarin ẹgbẹ oṣelu rẹ.

Gomina Rochas Okorocha ti ipinlẹ Imo kii ṣe ajeji si ariyanjiyan ati ede aiyede. Bi o ti ṣe n wọ iya ija ariyanjiyan pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC naa loun atawọn ti ipinlẹ rẹ pẹlu n waa ko.

Amọṣa, nibayii Gomina Rochas Okorocha ti ni aigba imọran igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo lo fa wahala ti o n n koju ni ipinlẹ naa.

Mi ò ní ìyàwó nílé, àmọ́ mo ní ọmọ tó pọ̀-Saheed Oṣupa

Ọmọ ọgbọ́n ọdún pa bàbá rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSagbokoji, ìlú tó sún mọ́ ọ̀làjú pẹ́kípẹ́kí ṣùgbọ́n tí iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì kò sí

Ẹ gbọ naa, imọran wo ni Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo fun Gomina Okorocha ti ko gba naa?

Lasiko to fi n sọrọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi awọn akanse iṣẹ to ṣe ni ipinlẹ naa ni gomina Okorocha ti ṣe ijẹwọ yii.

O ni ni asiko ti igbakeji aarẹ ti kọkọ wa ba oun lalejo ni ipinlẹ Imo lo ti fun oun ni imọran lati maa fọnrere awọn iṣẹ ti oun ba n ṣe. Amọ'sa, Okorocha ni esi ti oun fun Oṣinbajo nigba naa ni pe owo ti oun yoo fi ṣe eto ṣiṣi awọn akanṣe iṣẹ naa, oun yoo lo fi kọ kilasi miran sawọn ileewe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

O ni aṣe igbẹyin nii dun oloku ada lọrọ oun yoo pada ja si nitori lẹyin o rẹyin ni oun to kọgbọn ninu ọrọ ti igbakeji aarẹ sọ.

"Inu mi dun loni pe ilu Owerri tii ṣe olu ilu ipinlẹ yii ti mo ba ni ipo abule ti de ipo olu ilu nitootọ. Mo ti gba amọran yin bayii, igbakeji aarẹ. Mo si mọ pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria yoo lee mọ bi nnkan ṣe n lọ ni ipinlẹ Imo.

"N ṣe lawọn eeyan n ṣi mi gbọ ninu gbogbo ilakaka mi lati gbe ipinlẹ Imo goke agba. Itara mi fun ipinlẹ Imo si ti sọ mi di ẹni ti ori rẹ ko pe, nitori o wumi lati yi gbogbo nnkan pada ni kiakia."

Ninu ọrọ rẹ igbakeji aarẹ, Yẹmi Oṣinbajo ṣe akawe Gomina Rochas gẹgẹ bii ẹni to ṣe ọpọ aṣeyọri, amọ ti ko pariwo aṣeyọri rẹ sita fun aye ri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionZainab Aliyu: Mo sọkún títí, ojé tán lóju mi ni àhámọ Saudi