Sakodji, ìlú tí kò ní iná fún ọgọ́ọ̀rún ọdún
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sagbokoji, ìlú tó sún mọ́ ọ̀làjú pẹ́kípẹ́kí ṣùgbọ́n tí iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì kò sí láti ọgọ́ọ̀rún ọdún

Awọn agba bọ, wọn ni nibi ti eeyan kan ti n sunkun airi eyin ni ẹnikan n sun airi ete bo tirẹ. Eyi ni ọrọ to ṣe kongẹ awọn eeyan ileto Sagbokodji ni ipinlẹ Eko.

Lati nnkan bi ọgọrun ọdun ti ileto naa ti wa, ko si ina ẹlẹntiriiki ni ilu naa. Bẹẹ si niyi, ilu ti a n wi yii ko jinna si awọn ilu nla ati ibugbe awọn eeyan jankanjankan ni ipinlẹ Eko.

Ẹ gbọ naa, bawo ni ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki o ṣe?