Osun elections: Adeleke gba iléẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà lọ pẹ̀lú agbẹjọ́rò àgbà mẹ́fà, òdú amòfin mẹ́tàdínlógún míràn

Sẹnetọ Ademọla Adeleke Image copyright Ademola adeleke
Àkọlé àwòrán Sẹ́nétọ̀ Ademọla Adeleke ń lépa àti yí ìdájọ́ iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó ní Gboyega Oyetọla ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló borí ìbò gómìnà l'Ọṣun padà.

Lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti fi idi Gboyega Oyetọla mulẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti gba ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lọ lati lee yi idajọ naa pada.

Lati lee rii pe didun lọsan so fun oun ni igbẹjọ naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti kede amofin agba mẹfa pẹlu awọn agba ọjẹ agbẹjọro mẹtadinlogun miran gẹgẹ bii ikọ ti yoo gbe awijare ẹjọ rẹ kalẹ niwaju awọn adajọ agba orilẹede yii ti yoo gbọọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adeleke ninu atẹjade kan ni oun ko reti ohun miran ni ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria bi ko ṣe ikede pe oun ni gomina ti ilu dibo yan. Awọn amofin agba, SAN ti yoo lewaju ikọ rẹ ni Onyeachi Ikpeazu SAN, N.O.O Oke, SAN; Dr Paul Ananaba, SAN; Emeka Etiaba, SAN; Emeka Okpoko, SAN; and Kehinde Ogunwuminju, SAN.

Awọn agba ọjẹ agbẹjọro ti yoo tun ṣoju rẹ ni Niyi Owolade, L.N.Iheanacho, Edmund Biriomoni, Wole Jimi-Bada aatawọn mẹta miran.

Ori pepele mẹrin ni Adeleke gbe ipẹjọ kotẹmilọrun rẹ le eleyi to fi n ke si ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lati da idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to kede Gboyega Oyetọla gẹgẹ bii gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ Ọṣun nu.